Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú O. Daf 139:14

Gbogbo Ǹkan Tí Mo Nílò
Ọjọ́ Mẹ́ta
Ọlọ́run ti lọ ṣáájú wa ó sì ń pa wá mọ́ ní ọwọ́ ẹ̀yìn. Gbogbo ìdojúkọ wa ló ti yanjú. Gbogbo àlàfo ìdojúkọ ló sì ti dí pẹ̀lú. Ìpèníjà kò lè dé bá a lójijì. Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì ọlọ́jọ́-mẹ́ta yìí ma gbà ẹ́ ní ìyànjú nípa òtítọ́ wípé Ọlọ́run ni Olùpèsè ohun tó tọ́, àti èyí tó yẹ, fún ìgbésí ayé rẹ.

Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ṣáájú Ìgbéyàwó
Ojọ́ Márùn-ún
Àwọn ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kìí wáyé fúnra rẹ̀. Ìrètí wa ni wípé o máa ṣàwárí àwọn ìhà, ìlànà àti àṣà tí o nílò láti sọ ìgbéyàwó di èyí tó ní àlàáfíà tó sì nípọn fún gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí ni a fà yọ látinú ìwée Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó Ṣáájú Ìgbéyàwó tí a tọwọ́ọ Nicky àti Sila Lee kọ, àwọn olùkọ̀wé tó kọ Ìwé Ìgbéyàwó Náà.

Dìde kí o tan ìmọ́lẹ̀
Ọjọ́ 5
Àwọn ènìyàn maá ń sọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé, "Kó gbogbo àníyàn rẹ tọ Ọlọ́run." Ṣé o tilẹ̀ ròó rí pé: Báwo ni mo ṣe lè ṣe èyí? Ìdíbàjẹ́ inú ayé ka 'ni l'áyà. Bí ó sì ti lè wù ọ́ tó láti tan ìmọ́lẹ̀ Jésù, ìwọ yíó máa wo òyé bí èyí yíó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbàtí ìwọ alára ń tiraka láti rí ìmọ́lẹ̀ yìí fún ara rẹ. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí ṣe àgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún Jésù nígbàtí ayé tiwa gan-an dàbí pé ó wà ní òkúnkùn.

Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tọ̀: Gbígba Ẹni Tí A Jẹ́
Ọjọ́ mẹ́fà
Pẹ̀lú onírúurú ohùn tí ó ńsọ fún wa irú ẹni tí a óò jẹ́, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé à ún jìjàkadì irúfẹ́ ènìyàn tí à ń pe ara wa. Ọlọ́run Kò fẹ́ kí á fi iṣẹ́ òòjọ́, ipò ìgbéyàwó, tàbí àṣìṣe júwe ara wa. Ó ún fẹ́ kí èrò Rẹ̀ jẹ́ àṣẹ tí ó gajù lórí ayé wa. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fà yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi òye inú gbé oun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí o jẹ́ kí o bàa lè gba irúfẹ́ ẹnití òun ṣe nínú Krístì.

Mí Ìdí Tẹ̀mí Sínu Ìgbéyàwó Rè
7 ọjọ
A mu láti ìwé tuntun rè " Ifé Ayègígùn," Gary Thomas sọ̀rọ̀ sínu àwon ìdí ayérayé ti ìgbéyàwó. Kọ̀ọ́ practical ohun èlò láti ìrànlọ́wọ́ siṣẹ́ ọnà ìgbéyàwó rè sínu ìbáṣepò onímìísí, to n tànkálẹ̀ ìgbé-ayé tẹ̀mí si àwọn ẹlòmíràn.

Ohun Méje Ti Bíbélì So Nípa Àníyàn
7 ọjọ
Gbogbo ojó lo ṣeé ṣe fún láti gbé oríṣiríṣi ìpèníjà titun sínú ayé wá. Àmó o dọ́gba pẹ̀lú bí pé ojó titun kòòkan màa bùn wá pèlú àwon àǹfààní to yá gágá. Ní ojó-méje onífọkànsìn èyí, ọmọ-ẹgbẹ́ agbo òṣìṣẹ́ ni YouVersion ràn è lówó láti sílò òtítọ́ láti ínú òrò Olórun si ohun yòó wù ti ọ́ ń dojúko lòní. ífọkànsìn ojó kòòkan kún un ni Esẹ Bíbélì alàwòrán láti ràn è lówó láti ba o pín ohun ti Olórun n sọ̀rọ̀ sí o.

Ẹ̀mí Mímọ́: Ǹjẹ́ A Gba Iná Jẹ Àbí A Se Ìdáàbòbò Kí á má baà Gba Iná Jẹ?
Ọjọ́ méje
Agbára àgbàyanu, tó ń jí òkú dìde ḿbẹ nínú rẹ. Ajíhìnrere Reinhard Bonnke ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ àti wípé ó kọ àwọn Kókó Àgbàyanu nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Méje yìí ma mú ọ ronú nípa Ẹ̀mí Mímọ́ àti wípé ó máa ru ọ́ sókè láti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí náà tó ń gbé nínú rẹ.

Wiwá Àlàáfíà
Ojó Méwàá
Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.