Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Owe 22:6

Ohun méje tí Bíbélì sọ nípa jijẹ òbí
Ojó Méjé
Itọju ọmọ jẹ ohun tí o le púpò, pàápàá nínú ipò ti o dára jùlọ. Nínú ètò ọlọjọ méje yìí, àwọn òbí - ti wọn tún jẹ oṣiṣẹ ní YouVersion - pin nípa bí wọn se nlo ẹkọ nínú ọrọ Ọlọrun fún nkan tí o se pàtàkì yìí. Ètò ojoojumọ wá pẹlu ẹsẹ Bíbélì alaworan tí yíò ran ọ lọwọ láti pin nípa ìrìn àjò jíjẹ òbí n'itire.

Ọgbọ̀n tó Múná-dóko: Ìrìn-àjò Ọjọ́ Méje fún Àwọn Bàbá
Ọjọ́ méje
Ó máa ń yani lẹ́nu ìwọ̀n ipa tí bàbá kó nínú irú ẹ̀yán tí a jẹ́. Kò sí ẹnì náà tó lè bọ́ lọ́wọ́ agbára àti ipáa bàbá tíó bí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin kò ṣe tán láti di bàbá, ó ṣe pàtàkì fún wọn láti wá ìtọ́ni – láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ àwọn bàbá míràn. Ọgbọ́n tó múná-dóko jẹ́ ìrìn-àjò lọ sí ipa ọgbọ́n àti ìrírí fún àwọn bàbá, nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà àti ọgbọ́n láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìṣúra ìrírí ọ̀kan nínú àwọn bàbá tó dàgbà jù wá lọ, tíó ti k'ọ́gbọ́n nípasẹ̀ àwọn àṣìṣe rẹ̀.