Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 7:8

ỌLỌ́RUN + ÌLÉPA: Ọ̀nà Láti Gbé Ìlépa Kalẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Kristẹni
Ojọ́ Márùn-ún
Ǹjẹ́ o dára láti ní ìlépa gégé bí Kristẹni? Báwo ní o ṣe lẹ̀ mọ̀ tí ìlépa rẹ bá wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tàbí ara rẹ? Àti wípé báwo ni ìlépa Kristẹni ṣe rí ní pàtó? Nínú ètò kíkà ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí, o máa ṣàwárí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti rí ìtọ́sọ́nà lórí gbígbé ìlépa tó kún fún ore-ọ̀fẹ́ kalẹ̀!

Lilépa Káróòtì
Ọjọ́ méje
Gbogbo wá ló ǹ lépa nǹkan kan.O sábà máa ń jẹ́ nǹkan tí kò sí lárọ́wọ́tó bíi—iṣẹ́ tó dára, ilé tó tún dára,ìdílé pípé, àfọwọ́sí àwọn ẹlòmíràn. Àmó ńjẹ́ èyí kì í múni se àárẹ̀? See kò sí ọ̀nà mìíràn tó dára ni? Ṣe ìwádìí nínú ètò Bíbélì titun tí Life.Church, tí ń tè lé onírúurú ìwàásù Pastor Craig Groeschel nípa, lílépa kárọ́ọ̀tì.

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ojo Méjìlá
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!