← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 5:43

Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú Wúwo
Ọjọ́ Méje
Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.

Lilépa Káróòtì
Ọjọ́ méje
Gbogbo wá ló ǹ lépa nǹkan kan.O sábà máa ń jẹ́ nǹkan tí kò sí lárọ́wọ́tó bíi—iṣẹ́ tó dára, ilé tó tún dára,ìdílé pípé, àfọwọ́sí àwọn ẹlòmíràn. Àmó ńjẹ́ èyí kì í múni se àárẹ̀? See kò sí ọ̀nà mìíràn tó dára ni? Ṣe ìwádìí nínú ètò Bíbélì titun tí Life.Church, tí ń tè lé onírúurú ìwàásù Pastor Craig Groeschel nípa, lílépa kárọ́ọ̀tì.