Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Jak 1:22

Ilọsiwaju igbagbọ
3 Awọn ọjọ
Ninu ifọkansi ti ọsẹ yii, a fẹ lati wo awọn ipele oriṣiriṣi ti o waye ṣaaju ki igbagbọ eniyan le gbe awọn abajade ojulowo ati deede jade. Adura mi ni pe ki oluka yoo lo awọn ilana ti yoo pin nibi ni ọsẹ yii ni orukọ Jesu.

Bí A Ṣe Lè Ka Bíbélì (Àwọn Ìpìlẹ̀)
Ọjọ́ 5
Ó rọrùn láti rẹ̀wẹ̀sì, láti rò pé a kò múra tó, tàbí pé a kò ní ìtọ́sọ́nà ní ìgbà tí ó bá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èrò mi ni láti mú ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọrùn fún ọ ní àwọn ọ̀nà díẹ̀ nípa kíkọ́ ọ ní mẹ́ta nínú àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ láti ṣe àṣeyọrí nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. D'ara pọ̀ mọ́ ètò yìí kí o ṣe àwárí bí o ṣe lè ka Bíbélì, kìí ṣe fún àlàyé nìkan, ṣùgbọ́n fún ìyípadà ìgbésí ayé lónìí!

Dídàgbà Nínú Ìfẹ́
Ọjọ́ 5
Ohun tí ó ṣe pàtàkí ní pàtó ní fífẹ́ Ọlọ́run àti fífẹ́ ọmọlàkejì, ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe ṣe èyí dé ojú àmì? Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, a kò lè ní ìfẹ́ ẹlòmíràn dunjú nínú agbára ti ara wa. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá gbé ojú s'ókè sí Ọlọ́run tí a rẹ ara wa s'ílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀, a lè gbé ayé láti inú ògidì ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ní agbára. Kọ́ síi nípa dídàgbà nínú ìfẹ́ nínú Ètò-ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọ́jọ́-5 láti ọwọ́ Olùṣọ́-àgùntàn Amy Groeschel.