Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Gẹn 18:12

ÌGBÀGBỌ́; Ọ̀nà láti WU ỌLỌ́RUN
3 Awọn ọjọ
Ìrìn-àjò Kristẹni jẹ́ èyí tí a kò ti rí Ọlọ́run lójú-kojú, a máa ń bá A ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ọ̀nà kan ṣoṣo láti wu Ọlọ́run nínú ìrìn wa pẹ̀lú Rẹ̀ ni ìgbàgbọ́, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé a kò lè rí I pẹ̀lú ojú wa nípa tara. À ń gbọ́ Ọ nípa ìgbàgbọ́, à ń bá A sọ̀rọ̀ nípa Ìgbàgbọ́, a sì ń tọ̀ Ọ́ lọ nínú àdúrà nípa ìgbàgbọ́.

Jí Jókòó Níbi Ìdákẹ́ Rọ́rọ́: Ọjọ́ 7 Lórí Dí Dúró Sínú Ìlérí Ọlọ́run
Ọjọ́ Méje
Àwọn àkókò kan tí a gbá ìlérí Ọlọ́run mú, ṣùgbọ́n a kò rí ayé wa kí ó máa dọ́gba pẹ̀lú ìlérí náà tí Ọlọ́run fún wa. Ẹ̀wẹ̀ àkókò wà tí a bára wa ní oríta ní ìrìnàjò ayé wa, nígbàtí à ń gbára lé Ọlọ́run láti darí ipa ọ̀nà ayé wa, ṣùgbọ́n ìdákẹ́ rọ́rọ́ ni ohùn tó fọ̀ sí wa. Ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-7 yìí yóò sọ̀rọ̀ sí ọkàn rẹ nípa bí a ti ún rìn nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nígbàtí ó dàbíi pé Ó dákẹ́ jẹ́.

Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí Kérésìmesì
Ojó Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n
Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.