Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Iṣe Apo 1:6

Ìkéde-Ìhìnrere; Ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo onígbàgbọ́.
3 Awọn ọjọ
Ìbí, ikú àti àjíǹde Jésù mú ìròyìn ayọ̀ náà wá. Ìròyìn ayọ̀ yìí ni ó ti yọrí sí ìgbàlà arayé. Nítorí náà, gbogbo ẹni tí a ti gbàlà ni Jésù Olúwa àti Olùgbàlà ti pa á láṣẹ fún láti dìde fún ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ ìkéde-ìhìnrere, èyí tíí ṣe pínpín ìròyìn ayọ̀ yìí kan náà fún àwọn ẹlòmíràn tí kò tíì di ẹni ìgbàlà.

Èmi Mímọ́ Wá - Ìrìn Àjò Nínú Ìwé Ìṣe àwọn Aposteli - Pẹ̀lú Lumo
7 Awọn ọjọ
Ṣàwárí agbára àti wíwàà ti Èmi Mímọ́ nípa kika ètò ayínipadà yìí. Ó wá pẹ̀lú fídíò tí LUMO Lórí ìwé Iṣẹ́ àwọn Aposteli, yóò mú imo rẹ jìnlẹ̀ nípa ẹni tí Èmi Mímọ́ jẹ́, àti bí o ṣé ń ṣiṣẹ́ nínú àti nípasẹ̀ àwọn onígbàgbọ́ nígbà yẹn àti ní ìsinsìyìí. Gbáradì láti rí bí agbára rẹ̀ ṣe máa ṣiṣẹ́ láìlópin nínú àti nípasẹ̀ ayé rẹ bí oò ṣe tíì ri rí.

Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀
Ọjọ́ 21
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!