Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Pet 1:22

Àwọn Irúgbìn: Kíni àti Ìdí
Ọjọ́ 4
Àwọn irúgbìn wà níbi gbogbo. Ọ̀rọ̀ rẹ, owó rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti ìwọ alára, je irúgbìn! Báwo làwọn irúgbìn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa? Ẹ jẹ́ kí á wo ohun tí Bíbélì ní láti sọ, kí a sì wá rí bí ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé wa láti sún mọ́ Ọlọ́run àti ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa.

1 Peteru
5 Awọn ọjọ
Nípa ìrètí rẹ̀ nínú lẹ́tá tí ó ko sí ìjọ àkọ́kọ́, Peteru gbà wá níyànjú kí a ní ìgbàgbọ́, kí á sì gbọ́ràn. Ó ní kí á dúró sinsin nínú ìgbàgbọ́ nígbà tí a bá ń kojú àdánwò àti inúnibíni. Ó ní nítorí ẹ̀dá tí a jẹ́ nínú Jésù, a ní agbára láti gbé ìgbá ayé ìwà mímọ́, a ó sì le ní àfojúsùn ogún ayérayé.

Wiwá Àlàáfíà
Ojó Méwàá
Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.