Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Joh 4:8

Já Ara Rẹ Gbà Kúrò Lọ́wọ́ Owú Ètò Kíkà Ọlọ́jọ́-Mẹ́fà Látọwọ́ Anna Light
Ọjọ́ mẹ́fà
Ní àkókò yí, ǹkan tó dára nípa ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní wọ́n fihàn fún wa láti rí, àti wípé àfiwé tí a bá ṣe pẹ̀lú ayé tiwa a máa mú owú jẹyọ. O kò fẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí máa jọba nínú ayé rẹ, àmọ́ kí ló máa ṣe sí àwọn ìjàmbá tó lè wá nípasẹ̀ owú látọ̀dọ̀ ẹlòmíràn sí ọ? Nínú ètò kíkà yí, o máa rí àwọn ọ̀nà tí o lè gbà borí owú, pa ọkàn rẹ mọ́, pẹ̀lú òmìnira.

20/20: A Ti Rí. A Ti Yàn. A Ti Rán. Nípasẹ̀ Christine Caine
Ọjọ́ 7
Ǹjẹ́ o le fi ojú inú wòó bí yíò ṣe rí kí Ọlọ́run rí ọ lọ́nà tí ó jẹ́ wípé ìwo gan ò lè má ṣe aláìrì àwọn ẹlòmíràn? Ṣé o le fi ojú inú wòó wípé lójoojúmọ́, kí ìgbésí ayé rẹ̀ máa ní ipa tí ó ṣe pàtàkì nípa ìyè ayérayé? Ìfọkànsí ọlọ́jọ́ méje yìí, tí a kọ láti ọwọ́ Christine Caine yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí bí Ọlọ́run ṣe rí o, tí ó yàn ọ́, àti bí Ó ṣe rán ọ láti rí àwọn ẹlòmíràn àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wón le rí ara wọn bí Ọlọ́run ṣe rí wọn- pẹ̀lú ìríran 20/20.

Ara Èké
7 Awọn ọjọ
Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.

Kíni Ìfẹ́ Tòótọ́?
Ojo Méjìlá
Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ mọ̀ ohun ti ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Sùgbọ́n ènìyàn péréte ló màá ń wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àkòrí inú Bíbélì àti ìsúra tó ṣe pàtàkí jùlọ ní ìgbé-ayé Krìstìẹ́nì. Ẹ̀kọ́ yìí làti Ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend ṣe àgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ ìfẹ́ ní ìlànà Bíbélì àti bí a ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn.

Bàbá Fẹ́ràn Rẹ láti ọwọ́ Pete Briscoe
Ọjọ́ 16
A ti kọ́ wa láti kékeré pé Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níní ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá kì í rọrùn nígbà gbogbo—àgàgà bí àwọn bàbá wa ti orí ilẹ̀ ayé bá ń sapá láti fi ìfẹ́ tí a ń fẹ́ hàn wá. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rìndínlógún yìí, Pete Briscoe fa àfiyèṣí wa ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ń tẹ́ gbogbo àwọn èròngbà ìfẹ́ lọ́rùn—ó ń fi hàn bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé ó jẹ́ Bàbá wa rere àti Bàbá wa pípé.