Johanu Ìfáàrà
Ìfáàrà
Ìfáàrà sí ìwé Ìyìnrere Johanu
A kọ ìwé ìyìnrere Jesu láti ọwọ́ Johanu lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Jesu kú tí ó sì jí dìde láti ọwọ́ aposteli Johanu fún ète pàtàkì pé, gbogbo ẹni tó bá kà á yóò gbàgbọ́ nínú Kristi, yóò ní ìyè láti ipasẹ̀ orúkọ rẹ̀ (20.31). Ìwé ìyìnrere Johanu bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣáájú tí kò lẹ́gbẹ́. Ó fi Jesu hàn nínú ìyìnrere yìí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣáájú àkókò tí a bí I. Ó ṣàpèjúwe àwọn iṣẹ́ ìyanu àti ìkọ́ni rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ju èyí tí àwọn aṣíwájú ti sọ nípa rẹ̀ lọ. Ó fi ààyè tí ó gbòòrò sílẹ̀ (14.17) láti fi ṣe àpèjúwe bí Jesu ṣe kọ́ àwọn aposteli kí ó tó kú, lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jesu. Ó fi ààyè kan jìn ìfarahàn Jesu sí àwọn aposteli.
Ìwé Ìyìnrere Johanu ṣe àtẹnumọ́ ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi àti ìtumọ̀ ìgbé ayé rẹ̀ ju àwọn ìwé ìyìnrere tókù lọ. Johanu fi ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tọ́ka sí àwọn nǹkan ti ẹ̀mí bí i ìmọ́lẹ̀ òtítọ́, ìfẹ́, olùṣọ́-àgùntàn rere, ẹnu-ọ̀nà, àjíǹde àti ìyè, oúnjẹ ìyè àti ọ̀pọ̀ mìíràn. Àwọn nǹkan iyebíye tí a rí nínú ìwé yìí fi ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ Jesu sí onígbàgbọ́ àti àlàáfíà tó ń wá láti inú ìgbẹ́kẹ̀lé Kristi hàn.
Kókó-ọ̀rọ̀
Ọ̀rọ̀ ìṣáájú tó fi Jesu hàn bí ìyè àìnípẹ̀kun 1.1-18.
Iṣẹ́ ìta gbangba ṣáájú ti Galili 1.19–4.54.
Iṣẹ́ ìta gbangba Jesu ní Galili àti ìwàyáàjà ní Jerusalẹmu 5.1–10.42.
Jíjí Lasaru dìde kúrò ní ipò òkú 11.1-57.
Ìparí iṣẹ́ ìta gbangba Jesu 12.1–13.38.
Ìkọ́ni tí Jesu ṣe gbẹ̀yìn 14.1–17.26.
Ikú àti àjíǹde Jesu 18.1–20.10.
Àjíǹde àti ìfarahàn Jesu 20.11–21.25.
ಪ್ರಸ್ತುತ ಆಯ್ಕೆ ಮಾಡಲಾಗಿದೆ:
Johanu Ìfáàrà: BMYO
ಹೈಲೈಟ್ ಮಾಡಿ
ಹಂಚಿಕೊಳ್ಳಿ
ಕಾಪಿ
ನಿಮ್ಮ ಎಲ್ಲಾ ಸಾಧನಗಳಲ್ಲಿ ನಿಮ್ಮ ಮುಖ್ಯಾಂಶಗಳನ್ನು ಉಳಿಸಲು ಬಯಸುವಿರಾ? ಸೈನ್ ಅಪ್ ಮಾಡಿ ಅಥವಾ ಸೈನ್ ಇನ್ ಮಾಡಿ
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
Used by permission of Biblica, Inc. All rights reserved worldwide.