O. Daf 36:1-4
O. Daf 36:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
IREKỌJA enia buburu wi ninu ọkàn mi pe; ẹ̀ru Ọlọrun kò si niwaju rẹ̀. Nitoriti o npọ́n ara rẹ̀ li oju ara rẹ̀, titi a o fi ri ẹ̀ṣẹ rẹ̀ lati korira; Ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ li ẹ̀ṣẹ on ẹ̀tan: o ti fi ọgbọ́n ati iṣe rere silẹ, O ngbèro ìwa-ika lori ẹni rẹ̀: o gba ọ̀na ti kò dara; on kò korira ibi.
O. Daf 36:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú, kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀. Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀, pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun, ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi. Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró; kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́. A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀; a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́; kò sì kórìíra ibi.
O. Daf 36:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé; Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn. Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra. Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn; wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀; Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn: wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.