O. Daf 129:1-8
O. Daf 129:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
IGBA pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá, ni ki Israeli ki o wi nisisiyi. Igba pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá: sibẹ nwọn kò ti ibori mi. Awọn awalẹ̀ walẹ si ẹhin mi: nwọn si la aporo wọn gigun. Olododo li Oluwa: o ti ke okùn awọn enia buburu kuro. Ki gbogbo awọn ti o korira Sioni ki o dãmu, ki nwọn ki o si yi ẹhin pada. Ki nwọn ki o dabi koriko ori-ile ti o gbẹ danu, ki o to dagba soke: Eyi ti oloko pipa kò kún ọwọ rẹ̀; bẹ̃li ẹniti ndi ití, kò kún apa rẹ̀. Bẹ̃li awọn ti nkọja lọ kò wipe, Ibukún Oluwa ki o pẹlu nyin: awa sure fun nyin li orukọ Oluwa.
O. Daf 129:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé, “Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi, sibẹ, wọn kò borí mi.” Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn, gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko. Ṣugbọn olódodo ni OLUWA, ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú. Ojú yóo ti gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni, a óo lé wọn pada sẹ́yìn. Wọn óo dàbí koríko tí ó hù lórí òrùlé, tí kì í dàgbà kí ó tó gbẹ. Kò lè kún ọwọ́ ẹni tí ń pa koríko; kò sì lè kún ọwọ́ ẹni tí ń di koríko ní ìtí. Àwọn èrò ọ̀nà kò sì ní kí ẹni tí ń gé e pé: “OLUWA óo fèrè síṣẹ́ o! Ẹ kúuṣẹ́, OLUWA óo fèrè sí i.”
O. Daf 129:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá” ni kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí; “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá; síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi. Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi: wọ́n sì la aporo wọn gígùn. Olódodo ni OLúWA: ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.” Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú, kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà. Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀ tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè: Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀: bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé, ìbùkún OLúWA kí ó pẹ̀lú yín: àwa ń súre fún yin ní orúkọ OLúWA.