Lef 6:1-30

Lef 6:1-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose pe, Bi ẹnikan ba ṣẹ̀, ti o dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ti o si sẹ́ fun ẹnikeji rẹ̀, li ohun ti o fi fun u pamọ́, tabi li ohun ti a fi dógo, tabi ohun ti a fi agbara gbà, tabi ti o rẹ ẹnikeji rẹ̀ jẹ; Tabi ti o ri ohun ti o nù he, ti o si ṣeké nitori rẹ̀, ti o si bura eké; li ọkan ninu gbogbo ohun ti enia ṣe, ti o ṣẹ̀ ninu rẹ̀: Yio si ṣe, bi o ba ti ṣẹ̀, ti o si jẹbi, ki o si mú ohun ti o fi agbara gbà pada, tabi ohun ti o fi irẹjẹ ní, tabi ohun ti a fi fun u pamọ́, tabi ohun ti o nù ti o rihe. Tabi gbogbo eyi na nipa eyiti o bura eké; ki o tilẹ mú u pada li oju-owo rẹ̀, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si fi i fun olohun, li ọjọ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀. Ki o si mú ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wá fun OLUWA, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran tọ̀ alufa wá, ni idiyele rẹ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: Alufa yio si ṣètutu fun u niwaju OLUWA, a o si dari rẹ̀ jì; nitori ohunkohun ninu gbogbo ohun eyiti o ti ṣe ti o si jẹbi ninu rẹ̀. OLUWA si sọ fun Mose pe, Paṣẹ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ sisun: Ẹbọ sisun ni, nitori sisun rẹ̀ lori pẹpẹ ni gbogbo oru titi di owurọ̀, iná pẹpẹ na yio si ma jò ninu rẹ̀. Ki alufa ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ rẹ̀ wọ̀, ati ṣòkoto ọ̀gbọ rẹ̀ nì ki o fi si ara rẹ̀, ki o si kó ẽru ti iná jọ, ti on ti ẹbọ sisun lori pẹpẹ, ki o si fi i si ìha pẹpẹ. Ki o si bọ́ ẹ̀wu rẹ̀ silẹ, ki o si mú ẹ̀wu miran wọ̀, ki o si gbé ẽru wọnni jade lọ sẹhin ibudó si ibi kan ti o mọ́. Ki iná ori pẹpẹ nì ki o si ma jó lori rẹ̀; ki a máṣe pa a; ki alufa ki o si ma kòná igi lori rẹ̀ li orowurọ̀, ki o si tò ẹbọ sisun sori rẹ̀; ki o si ma sun ọrá ẹbọ alafia lori rẹ̀. Ki iná ki o ma jó titi lori pẹpẹ na; kò gbọdọ kú lai. Eyi si li ofin ẹbọ ohunjijẹ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o ru u niwaju OLUWA, niwaju pẹpẹ. Ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun didara ẹbọ ohunjijẹ na, ati ti oróro rẹ̀, ati gbogbo turari ti mbẹ lori ẹbọ ohunjijẹ, ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn, ani fun iranti rẹ̀, si OLUWA. Iyokù rẹ̀ ni Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio jẹ: àkara alaiwu ni, ki a jẹ ẹ ni ibi mimọ́; ni agbalá agọ́ ajọ ni ki nwọn ki o jẹ ẹ. Ki a máṣe fi iwukàra yan a. Mo ti fi i fun wọn ni ipín ti wọn ninu ẹbọ mi ti a fi iná ṣe; mimọ́ julọ ni, bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ ẹbi. Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn ọmọ Aaroni ni ki o jẹ ninu rẹ̀, yio jasi aṣẹ titilai ni iraniran nyin, nipa ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: ẹnikẹni ti o ba kàn wọn yio di mimọ́. OLUWA si sọ fun Mose pe, Eyi li ọrẹ-ẹbọ Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn o ru si OLUWA, li ọjọ́ ti a fi oróro yàn a; idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ titilai, àbọ rẹ̀ li owurọ̀, ati àbọ rẹ̀ li alẹ. Ninu awopẹtẹ ni ki a fi oróro ṣe e; nigbati a ba si bọ̀ ọ, ki iwọ ki o si mú u wọ̀ ile: ati ìṣu yiyan ẹbọ ohunjijẹ na ni ki iwọ ki o fi rubọ õrùn didùn si OLUWA. Ati alufa ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti a fi oróro yàn ni ipò rẹ̀ ni ki o ru u: aṣẹ titilai ni fun OLUWA, sisun ni ki a sun u patapata. Nitori gbogbo ẹbọ ohunjijẹ alufa, sisun ni ki a sun u patapata: a kò gbọdọ jẹ ẹ. OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ni ibi ti a gbé pa ẹbọ sisun, ni ki a si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ niwaju OLUWA: mimọ́ julọ ni. Alufa ti o ru u fun ẹ̀ṣẹ ni ki o jẹ ẹ: ni ibi mimọ́ kan ni ki a jẹ ẹ, ninu agbalá agọ́ ajọ. Ohunkohun ti o ba kàn ẹran rẹ̀ yio di mimọ́: nigbati ẹ̀jẹ rẹ̀ ba si ta sara aṣọ kan, ki iwọ ki o si fọ̀ eyiti o ta si na ni ibi mimọ́ kan. Ṣugbọn ohunèlo àmọ, ninu eyiti a gbé bọ̀ ọ on ni ki a fọ́; bi a ba si bọ̀ ọ ninu ìkoko idẹ, ki a si fọ̀ ọ, ki a si ṣìn i ninu omi. Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: mimọ́ julọ ni. Kò si sí ẹbọ ẹ̀ṣẹ kan, ẹ̀jẹ eyiti a múwa sinu agọ́ ajọ, lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ti a gbọdọ jẹ: sisun ni ki a sun u ninu iná.

Lef 6:1-30 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose, pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nípa ṣíṣe èyíkéyìí ninu nǹkan wọnyi: kì báà jẹ́ pé ó kọ̀ láti dá ohun tí aládùúgbò rẹ̀ fi dógò pada ni, tabi pé ó ja aládùúgbò rẹ̀ lólè ni, tabi pé ó rẹ́ ẹ jẹ ni, tabi pé ó rí nǹkan rẹ̀ tí ó sọnù he, tí ó sì ṣe bí ẹni pé òun kò rí i, tabi tí ó búra èké nípa ohunkohun, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó dá. Bí ẹnikẹ́ni bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó dá ohun tí ó jí pada, tabi ohun tí ó fi ìrẹ́jẹ gbà, tabi ohun tí wọ́n fi dógò lọ́dọ̀ rẹ̀, tabi ohun tí ó sọnù tí ó rí he, tabi ohunkohun tí ó ti búra èké sí. Kí ó san án pé pérépéré kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, nígbà tí ó bá dá ohun náà pada fún olúwarẹ̀, ní ọjọ́ tí yóo bá rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi. Kí ó mú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi tọ alufaa wá, ohun ìrúbọ náà ni àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ó rí i pé àgbò náà tó iye tí eniyan lè ra ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún ẹni náà níwájú OLUWA, OLUWA yóo sì dárí ohunkohun tí ó bá ṣe jì í.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Pa á láṣẹ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹbọ sísun: ẹbọ sísun níláti wà lórí ààrò lórí pẹpẹ ní gbogbo òru títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iná sì níláti máa jò lórí pẹpẹ náà ní gbogbo ìgbà. Kí alufaa wọ ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ funfun rẹ̀, ati ṣòkòtò aṣọ funfun, kí ó kó eérú ẹbọ tí ó ti fi iná sun kúrò lórí pẹpẹ, kí ó sì dà á sí ibìkan. Lẹ́yìn náà, kí ó bọ́ aṣọ iṣẹ́ alufaa rẹ̀ kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí ó wá ru eérú náà jáde kúrò ninu àgọ́ sí ibi mímọ́ kan. Kí iná orí pẹpẹ náà sì máa jó, kò gbọdọ̀ kú nígbà kan. Kí alufaa máa kó igi sí i ní àràárọ̀; kí ó máa to ẹbọ sísun lé e lórí, orí rẹ̀ ni yóo sì ti máa sun ọ̀rá ẹran tí ó bá fi rú ẹbọ alaafia. Iná orí pẹpẹ náà gbọdọ̀ máa jó nígbà gbogbo, kò gbọdọ̀ kú. “Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ohun jíjẹ. Àwọn ọmọ Aaroni ni yóo máa rúbọ náà níwájú pẹpẹ, níwájú OLUWA. Ọ̀kan ninu wọn yóo bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀, yóo sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA ni. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo jẹ ìyókù, láì fi ìwúkàrà sí i. Ibi mímọ́ kan ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni wọ́n ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Wọn kò gbọdọ̀ fi ìwúkàrà sí i, bí wọ́n bá fi ṣe burẹdi, èmi ni mo fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn ninu ẹbọ sísun mi; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ìmúkúrò ẹ̀bi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọkunrin ninu àwọn ọmọ Aaroni lè jẹ ninu rẹ̀, èyí ni ìlànà mi títí ayérayé láàrin arọmọdọmọ yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ẹbọ wọnyi yóo di mímọ́.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Ẹbọ tí àwọn ọmọ Aaroni yóo máa rú, ní ọjọ́ tí wọ́n bá fi wọ́n joyè alufaa nìyí: Ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, ìdajì rẹ̀ ní òwúrọ̀, ìdajì tí ó kù ní àṣáálẹ́. Kí wọ́n fi òróró po ìyẹ̀fun náà dáradára, kí wọ́n tó yan án lórí ààrò, lẹ́yìn náà kí wọ́n rún un gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọ́n sì fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. Ẹni tí wọ́n bá yàn sí ipò olórí alufaa lẹ́yìn Aaroni ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo máa rú ẹbọ yìí sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí ìlànà títí lae, gbogbo ìyẹ̀fun náà ni yóo fi rú ẹbọ sísun. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ninu ìyẹ̀fun ẹbọ ohun jíjẹ ti alufaa, gbogbo rẹ̀ ni kí wọ́n fi rú ẹbọ sísun.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran fún ẹbọ sísun, ni kí wọ́n ti máa pa ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ pẹlu, níwájú OLUWA; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ. Alufaa tí ó bá fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo jẹ ẹ́; níbi mímọ́, ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni kí ó ti jẹ ẹ́. Ohunkohun tí ó bá ti kan ẹran rẹ̀ di mímọ́; nígbà tí wọ́n bá sì ta lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára aṣọ kan, ibi mímọ́ ni wọ́n ti gbọdọ̀ fọ aṣọ náà. Fífọ́ ni wọ́n sì gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí wọ́n bá fi sè é, ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé ìkòkò idẹ ni wọ́n fi sè é, wọ́n gbọdọ̀ fi omi fọ̀ ọ́, kí wọ́n sì ṣàn án nù dáradára. Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ alufaa tí ó bá jẹ́ ọkunrin lè jẹ ninu ohun ìrúbọ yìí; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ. Ṣugbọn bí wọ́n bá mú ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sinu Àgọ́ Àjọ, tí wọ́n bá lò ó fún ètùtù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran náà, sísun ni wọ́n gbọdọ̀ sun ún.

Lef 6:1-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí OLúWA nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ, tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀. Bí ó bá dẹ́ṣẹ̀ báyìí tó sì jẹ̀bi, ó gbọdọ̀ dá ohun tó jí tàbí ohun tó fi agbára gbà, tàbí ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ̀, tàbí ohun tó sọnù tó rí he, tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí. Ó gbọdọ̀ dá gbogbo rẹ̀ padà ní pípé, kí ó fi ìdámárùn-ún iye rẹ̀ kún, kí ó sì dá gbogbo rẹ̀ padà fún ẹni tí ó ni í, ní ọjọ́ tó bá ń rú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀. Fún ìtánràn rẹ̀, ó gbọdọ̀ mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá fún àlùfáà, àní síwájú OLúWA, ẹbọ ẹ̀bi, àgbò aláìlábùkù, tó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. Báyìí ní àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ níwájú OLúWA, a ó sì dáríjì í nítorí ohun tó ti ṣe tó sì mú un jẹ̀bi.” OLúWA sọ fún Mose pé: “Pàṣẹ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé: ‘Èyí ni ìlànà fún ẹbọ sísun; ẹbọ sísun gbọdọ̀ wà lórí pẹpẹ láti alẹ́ di òwúrọ̀, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ kí àlùfáà sì wọ ẹ̀wù funfun rẹ̀ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì kó eérú tó wà níbi ẹbọ sísun tí iná ti jó lórí pẹpẹ, sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni yóò bọ́ aṣọ rẹ̀, yóò sì wọ òmíràn, yóò wá gbé eérú náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tí a kà sí mímọ́. Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀. Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú. “ ‘Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Aaroni gbé ẹbọ sísun náà wá síwájú OLúWA níwájú pẹpẹ. Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí OLúWA. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò jẹ ìyókù ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ láìsí máa wú máa wú ohun tí ń mú àkàrà wú nínú rẹ̀ ní ibi mímọ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé ni kí wọn ó ti jẹ ẹ́. Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú ìwúkàrà. Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi. Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́. Èyíkéyìí nínú àwọn ọmọkùnrin ìran Aaroni ló le jẹ ẹ́. Èyí ni ìpín rẹ tí ó gbọdọ̀ máa ṣe déédé lára àwọn ẹbọ tí a fi iná sun sí OLúWA láti ìrandíran. Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́.’ ” OLúWA sọ fún Mose pé, “Èyí ni ọrẹ tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún OLúWA ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́. Ẹ pèsè rẹ̀ pẹ̀lú òróró nínú àwo fífẹ̀, ẹ pò ó pọ̀ dáradára, kí ẹ sì gbé ọrẹ ohun jíjẹ náà wá ní ègé kéékèèkéé bí òórùn dídùn sí OLúWA. Ọmọkùnrin Aaroni tí yóò rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a fi òróró yàn ni yóò rú ẹbọ náà. Ó jẹ́ ìpín ti OLúWA títí láé, wọn sì gbọdọ̀ sun ún pátápátá. Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ ti àlùfáà ni wọ́n gbọdọ̀ sun pátápátá, wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.” OLúWA sọ fún Mose pé: “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ Ọkùnrin: ‘Wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ẹ sì pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLúWA, níbi tí ẹ ti ń pa ẹran ẹbọ sísun, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. Àlùfáà tó rú ẹbọ náà ni kí ó jẹ ẹ́, ibi mímọ́ ni kí ó ti jẹ ẹ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé. Ohunkóhun tí ó bá kàn án yóò di mímọ́, bí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá sì ta sí ara aṣọ kan, ẹ gbọdọ̀ fọ̀ ọ́ ní ibi mímọ́. Ẹ gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí ẹ fi se ẹran náà, ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìkòkò idẹ ni ẹ fi sè é, ẹ gbọdọ̀ bó o, kí ẹ sì fi omi sìn ín dáradára. Gbogbo ọkùnrin ní ìdílé àlùfáà ló lè jẹ ẹ́, ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kankan, èyí tí wọ́n bá mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ètùtù ní ibi mímọ́, sísun ni kí ẹ sun ún.