Job 36:26-28
Job 36:26-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiyesi i, Ọlọrun tobi, awa kò si mọ̀ bi o ti tobi to! bẹ̃ni a kò le wadi iye ọdun rẹ̀ ri. Nitoripe on li o fa ikán omi ojo silẹ, ki nwọn ki o kán bi ojo ni ikuku rẹ̀. Ti awọsanma nrọ̀, ti o si nfi sẹ̀ lọpọlọpọ lori enia.
Pín
Kà Job 36Job 36:26-28 Yoruba Bible (YCE)
Wò ó, Ọlọrun tóbi lọ́ba, ju ìmọ̀ wa lọ, kò sí ẹni tí ó lè mọ ọjọ́ orí rẹ̀. “Ó fa ìkán omi sókè láti inú ilẹ̀, ó sọ ìkùukùu di òjò, ó sì rọ òjò sílẹ̀ láti ojú ọ̀run sórí ọmọ eniyan lọpọlọpọ.
Pín
Kà Job 36Job 36:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí. “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀, kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀, tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.
Pín
Kà Job 36