Isa 53:1-5 - Compare All Versions

Isa 53:1-5 YBCV (Bibeli Mimọ)

TALI o ti gbà ihìn wa gbọ́? tali a si ti fi apá Oluwa hàn fun? Nitori yio dàgba niwaju rẹ̀ bi ọ̀jẹlẹ ohun ọ̀gbin, ati bi gbòngbo lati inu ilẹ gbigbẹ: irísi rẹ̀ kò dara, bẹ̃ni kò li ẹwà, nigbati a ba si ri i, kò li ẹwà ti a ba fi fẹ ẹ. A kẹgan rẹ̀ a si kọ̀ ọ lọdọ awọn enia, ẹni-ikãnu, ti o si mọ̀ ibanujẹ: o si dabi ẹnipe o mu ki a pa oju wa mọ kuro lara rẹ̀; a kẹgàn rẹ̀, awa kò si kà a si. Lõtọ o ti ru ibinujẹ wa, o si gbe ikãnu wa lọ; ṣugbọn awa kà a si bi ẹniti a nà, ti a lù lati ọdọ Ọlọrun, ti a si pọ́n loju. Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da.

Isa 53:1-5 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́ àti ta ni a ti fi apá OLúWA hàn fún? Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn, àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀. Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀ tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀. A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí. Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá. Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú, síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù, tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú. Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.

Isa 53:1-5 YCE (Yoruba Bible)

Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́? Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn? Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwé ati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ. Ìrísí rẹ̀ kò dára, ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan. Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀; ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni. Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà. A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún. Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ, ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa; sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà, tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa, wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa; ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia, nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.