Matiu 11:1-5

Matiu 11:1-5 BMYO

Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Galili gbogbo. Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?” Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí. Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìyìnrere fún àwọn òtòṣì.

Àwọn fídíò fún Matiu 11:1-5