Eksodu 21:12-25

Eksodu 21:12-25 BMYO

“Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu arákùnrin rẹ̀ pa, pípa ni a ó pa á. Ṣùgbọ́n bí kò bá mọ̀ ọ́n mọ̀ pa á, tí ó bá jẹ́ àmúwá Ọlọ́run ni, òun yóò lọ sí ibi tí èmi yóò yàn fún un. Ṣùgbọ́n tí ó bá mú arákùnrin rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀tàn pa á. Ẹ mú un kúrò ní iwájú pẹpẹ mi kí ẹ sì pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá jí ènìyàn gbé, tí ó sì tà á tàbí tí ó fi pamọ́, pípa ni a ó pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á. “Bí àwọn ọkùnrin méjì bá ń jà, ti ọ̀kan sọ òkúta tàbí fi ìkùùkuu lu ẹnìkejì rẹ̀, tí ó sì pa á lára, ti irú ìpalára bẹ́ẹ̀ mu kí ó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn. Ẹni tó lu ẹnìkejì rẹ̀ kò ní ní ẹ̀bi, níwọ̀n ìgbà ti ẹni tí a lù bá ti lè dìde, tí ó sì lé è fi ọ̀pá ìtìlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ rìn káàkiri. Ẹni náà ni láti san owó ti ó fi tọ́jú ara rẹ̀ padà fún un, lẹ́yìn ìgbà tí ara rẹ̀ bá ti yá tan pátápátá. “Bí ọkùnrin kan bá fi ọ̀pá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, ti ẹrú náà sì kú lójú ẹsẹ̀, a ó fi ìyà jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n a kò ní fi ìyà jẹ ẹ́, ti ẹrú náà bá yè, tí ó dìde lẹ́yìn ọjọ́ kan tàbí méjì, nítorí ẹrú náà jẹ́ dúkìá rẹ̀. “Bí àwọn ènìyàn ti ń jà bá pa aboyún lára, tí aboyún náà bá bímọ láìpé ọjọ́, ṣùgbọ́n tí kò sí aburú mìíràn mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ẹni tí ó fa ìpalára yìí yóò san iyekíye tí ọkọ aboyún náà bá béèrè fún, bí ilé ẹjọ́ bá ṣe gbà láààyè gẹ́gẹ́ bí owó ìtánràn. Ṣùgbọ́n bí ìpalára náà bá yọrí sí ikú aboyún náà, pípa ni a ó pa ẹni ti ó fa ikú aboyún náà. Ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀, ìjóná fún ìjóná, ọgbẹ́ fún ọgbẹ́, ìnà fún ìnà.