Daniẹli 10:9-14
Daniẹli 10:9-14 BMYO
Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí i, mo sùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀. Ọwọ́ kan kàn mí, ó gbé mi dìde ní ìwárìrì lórí ọwọ́ àti eékún mi. Ó sọ pé, “Daniẹli ẹni tí a yàn fẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀ wò dáradára, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ.” Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì. Nígbà náà ni ó tẹ̀síwájú, pé, “Má ṣe bẹ̀rù Daniẹli. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n ọmọ-aládé ìjọba Persia dá mi dúró fún ọjọ́ mọ́kànlélógún. Nígbà náà ni Mikaeli, ọ̀kan lára ìjòyè àwọn ọmọ-aládé, wá láti ràn mi lọ́wọ́, nítorí a dá mi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ọba Persia. Ní ìsinsin yìí mo wá láti ṣàlàyé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú, nítorí ìran náà ń sọ nípa ọjọ́ iwájú.”

