Ibukún ni fun enia na, ipá ẹniti o wà ninu rẹ: li ọkàn ẹniti ọ̀na rẹ wà. Awọn ti nla afonifoji omije lọ, nwọn sọ ọ di kanga; akọrọ-òjo si fi ibukún bò o. Nwọn nlọ lati ipá de ipá, ni Sioni ni awọn yọ niwaju Ọlọrun. Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, gbọ́ adura mi; fi eti si i, Ọlọrun Jakobu. Kiyesi i, Ọlọrun asà wa, ki o si ṣiju wò oju Ẹni-ororo rẹ. Nitori pe ọjọ kan ninu agbala rẹ sanju ẹgbẹrun ọjọ lọ. Mo fẹ ki nkuku ma ṣe adena ni ile Ọlọrun mi, jù lati ma gbe agọ ìwa-buburu. Nitori Oluwa Ọlọrun li õrun ati asà: Oluwa yio fun ni li ore-ọfẹ ati ogo: kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede. Oluwa awọn ọmọ-ogun, ibukún ni fun oluwarẹ̀ na ti o gbẹkẹle ọ.
Kà O. Daf 84
Feti si O. Daf 84
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 84:5-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò