Mat 12:44-46

Mat 12:44-46 YBCV

Nigbana ni o wipe, Emi o pada lọ si ile mi, nibiti mo gbé ti jade wá; nigbati o si de, o bá a, o ṣofo, a gbá a mọ́, a si ṣe e li ọṣọ. Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran pẹlu ara rẹ̀, ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn bọ si inu rẹ̀, nwọn si ngbé ibẹ̀; igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ. Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri fun iran buburu yi pẹlu. Nigbati o nsọ̀rọ wọnyi fun awọn enia, wò o, iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ duro lode, nwọn nfẹ ba a sọ̀rọ.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ