Jer 23:5-8

Jer 23:5-8 YBCV

Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na. Li ọjọ rẹ̀ ni a o gba Juda là, Israeli yio si ma gbe li ailewu, ati eyi li orukọ ti a o ma pè e: OLUWA ODODO WA. Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti nwọn kì yio tun wipe, Oluwa mbẹ, ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti: Ṣugbọn pe, Oluwa mbẹ, ti o mu iru-ọmọ ile Israeli wá, ti o si tọ́ wọn lati ilu ariwa wá, ati lati ilu wọnni nibi ti mo ti lé wọn si, nwọn o si gbe inu ilẹ wọn.