I. Tim 3:1-5

I. Tim 3:1-5 YBCV

OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ. Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ. Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo; Ẹniti o kawọ ile ara rẹ̀ girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀ tẹriba pẹlu ìwa àgba gbogbo; (Ṣugbọn bi enia kò ba mọ̀ bi ã ti ṣe ikawọ ile ara rẹ̀, on o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?)