Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi, kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má jẹ́ ọjọ́ ayọ̀. Ègún ni fún ẹni tí ó yọ̀ fún baba mi, tí ó sọ fún un pé, “Iyawo rẹ ti bí ọmọkunrin kan fún ọ, tí ó mú inú rẹ̀ dùn.” Kí olúwarẹ̀ dàbí àwọn ìlú tí OLUWA parun láìṣàánú wọn. Kí ó gbọ́ igbe lówùúrọ̀, ati ariwo ìdágìrì lọ́sàn-án gangan. Nítorí pé kò pa mí ninu oyún, kí inú ìyá mi lè jẹ́ isà òkú fún mi. Kí n wà ninu oyún ninu ìyá mi títí ayé. Kí ló dé tí wọn bí mi sáyé? Ṣé kí n lè máa fojú rí ìṣẹ́ ati ìbànújẹ́ ni? Kí gbogbo ọjọ́ ayé mi lè kún fún ìtìjú?
Kà JEREMAYA 20
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JEREMAYA 20:14-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò