YouVersion Logo
Search Icon

ẸKÚN JEREMAYA 1

1
Ìbànújẹ́ Jerusalẹmu
1Ẹ wò ó bí ìlú tí ó kún fún eniyan tẹ́lẹ̀ ti di ahoro,#Bar 4:12
tí ó wá dàbí opó!
Ìlú tí ó tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀!
Tí ó sì dàbí ọmọ ọba obinrin
láàrin àwọn ìlú yòókù.
Ó ti wá di ẹni àmúsìn.
2Ó ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lóru,
omijé ń dà lójú rẹ̀,
kò sì sí ẹni tí yóo tù ú ninu, láàrin àwọn alajọṣepọ rẹ̀.
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á,
wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn,
wọ́n sì di ọ̀tá rẹ̀.
3Juda ti lọ sí ìgbèkùn,
wọ́n sì ń fi tipátipá mú un sìn.
Nisinsinyii, ó ń gbé
ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,
kò sì ní ibi ìsinmi.
Ọwọ́ àwọn tí wọn ń lépa rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́,
ninu ìdààmú rẹ̀.
4Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Sioni ń ṣe ìdárò,
nítorí kò sí ẹni tí ó ń gba ibẹ̀ lọ
síbi àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ mọ́.
Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti di ahoro,
àwọn alufaa rẹ̀ sì ń kẹ́dùn.
Wọ́n ń pọ́n àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lójú,
òun pàápàá sì ń joró lọpọlọpọ.
5Àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Juda ti borí rẹ̀, wọ́n ti wá di ọ̀gá rẹ̀,
nítorí pé, OLUWA ń jẹ ẹ́ níyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
àwọn ọ̀tá ti ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣáájú,
wọ́n ti kó wọn nígbèkùn lọ.
6Gbogbo ògo Jerusalẹmu ti fò lọ kúrò lára rẹ̀,
àwọn olórí rẹ̀ dàbí àgbọ̀nrín
tí kò rí koríko tútù jẹ;
agbára kò sí fún wọn mọ́,
wọ́n ń sálọ níwájú àwọn tí ń lé wọn.
7Ní ọjọ́ ìpọ́njú ati ìbànújẹ́,
Jerusalẹmu ranti àwọn nǹkan iyebíye tí ó ní ní ìgbà àtijọ́.
Nígbà tí àwọn eniyan rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,
tí kò sì sí ẹni tí yóo ràn wọ́n lọ́wọ́.
Àwọn ọ̀tá bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ ọ́,
wọ́n sì ń fi ṣẹ̀sín nítorí ìṣubú rẹ̀.
8Jerusalẹmu ti dẹ́ṣẹ̀ burúkú,
nítorí náà ó ti di eléèérí.
Àwọn tí wọn ń bu ọlá fún un tẹ́lẹ̀ ti ń kẹ́gàn rẹ̀,
nítorí pé wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀.
Òun pàápàá ń kérora, ó sì fi ojú pamọ́.
9Ìwà èérí rẹ̀ hàn níbi ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀,
kò sì bìkítà fún ìparun tí ń bọ̀.
Nítorí náà ni ìṣubú rẹ̀ fi pọ̀, tí kò sì fi ní olùtùnú.
Ó ké pe OLUWA pé kí ó ṣíjú wo ìnira òun,
nítorí pé ọ̀tá ti borí rẹ̀.
10Ọ̀tá ti tọwọ́ bọ ilé ìṣúra rẹ̀,
wọ́n sì ti kó gbogbo nǹkan iyebíye inú rẹ̀ lọ;
ó ń wo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,
tí wọn ń wọ ibi mímọ́ rẹ̀.
Àwọn tí ó pàṣẹ pé
wọn kò gbọdọ̀ dé àwùjọ àwọn eniyan rẹ̀.
11Gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ń kérora
bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;
wọ́n ń fi ìṣúra wọn ṣe pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ
kí wọ́n baà lè lágbára.
Jerusalẹmu ń sunkún pé,
“Bojúwò mí, OLUWA,
nítorí pé mo di ẹni ẹ̀gàn.”
12Ó ní, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí kò kàn yín ni,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kọjá lọ?
Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, kí ẹ ṣe akiyesi rẹ̀,
bóyá ìbànújẹ́ kan wà
tí ó dàbí èyí tí ó dé bá mi yìí;
tí OLUWA mú kí ó dé bá mi,
ní ọjọ́ ibinu gbígbóná rẹ̀.
13“Ó rán iná láti òkè ọ̀run wá;
ó dá a sí egungun mi;
ó dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;
ó sì dá mi pada.
Mo dàbí odi,
mo sì fi ìgbà gbogbo dákú.
14“Ó di ẹ̀ṣẹ̀ mi bí àjàgà,
ó gbé e kọ́ mi lọ́rùn,
ó sì sọ mí di aláìlágbára.
OLUWA ti fi mí lé
àwọn tí n kò lè dojú kọ lọ́wọ́.
15“OLUWA ti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn akọni mi mọ́lẹ̀;
ó pe ọpọlọpọ eniyan jọ sí mi,
ó ní kí wọ́n pa àwọn ọdọmọkunrin mi;
OLUWA ti tẹ àwọn ọmọ Juda ní àtẹ̀rẹ́,
bí ẹni tẹ èso àjàrà fún ọtí waini.
16“Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi ni mo ṣe sọkún;
tí omijé ń dà lójú mi;
olùtùnú jìnnà sí mi,
kò sí ẹni tí ó lè dá mi lọ́kàn le.
Àwọn ọmọ mi ti di aláìní,
nítorí pé àwọn ọ̀tá ti borí wa.
17“Sioni na ọwọ́ rẹ̀ fún ìrànwọ́,
Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́,
OLUWA ti pàṣẹ pé,
kí àwọn aládùúgbò Jakọbu di ọ̀tá rẹ̀;
Jerusalẹmu sì ti di eléèérí láàrin wọn.
18“Ohun tí ó tọ́ ni OLUWA ṣe,
nítorí mo ti ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀;
ṣugbọn, ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan,
ẹ kíyèsí ìjìyà mi;
wọ́n ti kó àwọn ọdọmọbinrin ati ọdọmọkunrin mi
lọ sí ìgbèkùn.
19“Mo ké pe àwọn alajọṣepọ mi,
ṣugbọn títàn ni wọ́n tàn mí;
àwọn alufaa ati àwọn àgbààgbà mi ṣègbé láàrin ìlú,
níbi tí wọn ti ń wá oúnjẹ kiri,
tí wọn óo jẹ, kí wọn lè lágbára
20“Bojúwò mí, OLUWA,
nítorí mo wà ninu ìpọ́njú,
ọkàn mi ti dàrú, inú mi bàjẹ́,
nítorí pé mo ti hùwà ọ̀tẹ̀ lọpọlọpọ.
Níta gbangba, ogun ń pa mí lọ́mọ;
bákan náà ni ikú ń bẹ ninu ilé.
21“Gbọ́ bí mo ti ń kérora,
kò sí ẹnìkan tí yóo tù mí ninu.
Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa ìyọnu mi;
inú wọn sì dùn,
pé ìwọ ni o kó ìyọnu bá mi.
Jẹ́ kí ọjọ́ tí o dá tètè pé,
kí àwọn náà lè dàbí mo ti dà.
22“Ranti gbogbo ìwà ibi wọn,
kí o sì jẹ wọ́n níyà;
bí o ti jẹ mí níyà,
nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.
Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”

Currently Selected:

ẸKÚN JEREMAYA 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy