YouVersion Logo
Search Icon

JOHANU 9

9
Jesu Wo Ẹni tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú Sàn
1Bí Jesu ti ń kọjá lọ, ó rí ọkunrin kan tí ó fọ́jú láti inú ìyá rẹ̀ wá. 2Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé, “Olùkọ́ni, ta ni ó dẹ́ṣẹ̀, ọkunrin yìí ni, tabi àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n fi bí i ní afọ́jú?”
3Jesu dáhùn pé, “Ati òun ni, ati àwọn òbí rẹ̀ ni, kò sí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn kí iṣẹ́ Ọlọrun lè hàn nípa ìwòsàn rẹ̀ ni. 4Dandan ni fún mi kí n ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi ní ojúmọmọ, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ ṣú ná, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè ṣiṣẹ́. 5Níwọ̀n ìgbà tí mo wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”#Mat 5:14; Joh 8:12
6Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tutọ́ sílẹ̀, ó fi po amọ̀, ó bá fi lẹ ojú ọkunrin náà. 7Ó wí fún un pé, “Lọ bọ́jú ninu adágún tí ó ń jẹ́ Siloamu.” (Ìtumọ̀ Siloamu ni “rán níṣẹ́.”) Ọkunrin náà lọ, ó bọ́jú, ó bá ríran.
8Nígbà tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn tí wọn máa ń rí i tẹ́lẹ̀ tí ó máa ń ṣagbe, rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ọkunrin yìí kọ́ ni ó ti máa ń jókòó, tí ó máa ń ṣagbe rí?”
9Àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni!” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó jọ ọ́ ni.”
Ọkunrin náà ni, “Èmi gan-an ni.”
10Wọ́n bi í pé, “Báwo ni ojú rẹ́ ti ṣe là?”
11Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.”
12Wọ́n bi í pé, “Níbo ni ọkunrin náà wà?”
Ó dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀.”
Àwọn Farisi Wádìí Ìwòsàn Afọ́jú Náà
13Àwọn kan bá mú ọkunrin tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí yìí lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi. 14(Ọjọ́ Ìsinmi ni ọjọ́ tí Jesu po amọ̀, tí ó fi la ojú ọkunrin náà.) 15Àwọn Farisi tún bi ọkunrin náà bí ó ti ṣe ríran. Ó sọ fún wọn pé, “Ó lẹ amọ̀ mọ́ mi lójú, mo lọ bọ́jú, mo bá ríran.”
16Àwọn kan ninu àwọn Farisi ń sọ pé, “Ọkunrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nítorí kò pa òfin Ọjọ́ Ìsinmi mọ́.”
Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé “Báwo ni ẹni tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ìyanu yìí?” Ìyapa bá bẹ́ sáàrin wọn.
17Wọ́n tún bi ọkunrin afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ alára sọ nípa lílà tí ó là ọ́ lójú?”
Ọkunrin náà ní, “Wolii ni.”
18Àwọn Juu kò gbàgbọ́ pé ó ti fọ́jú rí kí ó tó ríran títí wọ́n fi pe àwọn òbí ọkunrin náà. 19Wọ́n bi wọ́n pé, “Ọmọ yín nìyí, tí ẹ sọ pé ẹ bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ti ṣe wá ríran nisinsinyii?”
20Àwọn òbí rẹ̀ dáhùn pé, “A mọ̀ pé ọmọ wa nìyí; ati pé afọ́jú ni a bí i. 21Ṣugbọn àwa kò mọ̀ bí ó ti ṣe wá ń ríran nisinsinyii. Ẹ bi í, kì í ṣe ọmọde, yóo fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bí ó ti rí.” 22Àwọn òbí rẹ̀ fèsì báyìí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu; nítorí àwọn Juu ti pinnu láti yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu ni Mesaya kúrò ninu àwùjọ. 23Nítorí èyí ni àwọn òbí ọkunrin náà ṣe sọ pé, “Kì í ṣe ọmọde, ẹ bi òun alára léèrè.”
24Wọ́n tún pe ọkunrin náà tí ó ti fọ́jú rí lẹẹkeji, wọ́n wí fún un pé, “Sọ ti Ọlọrun! Ní tiwa, àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkunrin yìí.”
25Ọkunrin náà sọ fún wọn pé, “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni o, tabi ẹlẹ́ṣẹ̀ kọ́, èmi kò mọ̀. Nǹkankan ni èmi mọ̀: afọ́jú ni mí tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, mo ríran.”
26Wọ́n bi í pé, “Kí ni ó ṣe sí ọ? Báwo ni ó ti ṣe là ọ́ lójú?”
27Ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ fun yín lẹ́ẹ̀kan ná, ṣugbọn ẹ kò fẹ́ gbọ́. Kí ló dé tí ẹ fi tún fẹ́ gbọ́? Àbí ẹ̀yin náà fẹ́ di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni?”
28Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bú u, wọ́n ní, “Ìwọ ni ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ní tiwa, ọmọ-ẹ̀yìn Mose ni wá. 29Àwa mọ̀ pé Ọlọrun ti bá Mose sọ̀rọ̀, ṣugbọn a kò mọ ibi tí eléyìí ti yọ wá.”
30Ọkunrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ohun ìyanu ni èyí! Ẹ kò mọ ibi tí ó ti yọ wá, sibẹ ó là mí lójú. 31A mọ̀ pé Ọlọrun kì í fetí sí ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn a máa fetí sí ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. 32Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé a kò rí i gbọ́ pé ẹnikẹ́ni la ojú ẹni tí wọ́n bí ní afọ́jú rí. 33Bí ọkunrin yìí kò bá wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, kì bá tí lè ṣe ohunkohun.”
34Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ìwọ yìí tí wọ́n bí ninu ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n tọ́ dàgbà ninu ẹ̀ṣẹ̀, o wá ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́!” Wọ́n bá tì í jáde.
Ìfọ́jú ti Ẹ̀mí
35Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ti ọkunrin náà jáde kúrò ninu ilé ìpàdé. Nígbà tí ó rí i, ó bí i pé, “Ìwọ gba Ọmọ-Eniyan gbọ́ bí?”
36Ọkunrin náà dáhùn pé, “Alàgbà, ta ni ẹni náà, kí n lè gbà á gbọ́?”
37Jesu wí fún un pé, “Èmi tí ò ń wò yìí, tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni ẹni náà.”
38Ọkunrin náà dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́, Oluwa!” Ó bá dọ̀bálẹ̀ fún un.
39Jesu bá ní, “Kí n lè ṣe ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran, kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”
40Farisi wà láàrin àwọn eniyan tí ó wà pẹlu rẹ̀, tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n bi í pé, “Àbí àwa náà fọ́jú?”
41Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ fọ́jú, ẹ kò bá tí ní ẹ̀bi. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ sọ pé, ‘Àwa ríran’ ẹ̀bi yín wà sibẹ.”

Currently Selected:

JOHANU 9: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy