YouVersion Logo
Search Icon

HEBERU 1

1
Ọlọrun Sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ̀
1Ní ìgbà àtijọ́, oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni Ọlọrun fi ń bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀. 2Ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó wá bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó fi ṣe àrólé ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá ayé.#Ọgb 7:22 3Ọmọ yìí jẹ́ ẹni tí ògo Ọlọrun hàn lára rẹ̀, ó sì jẹ́ àwòrán bí Ọlọrun ti rí gan-an. Òun ni ó mú kí gbogbo nǹkan dúró nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ eniyan nù tán, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá Ògo ní ibi tí ó ga jùlọ.#Ọgb 7:25-26; 8:1
Ọmọ Ọlọrun Ju Àwọn Angẹli Lọ
4Ó ní ipò tí ó ga ju ti àwọn angẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ní orúkọ tí ó ju tiwọn lọ. 5Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé,
“Ìwọ ni ọmọ mi,
lónìí ni mo bí ọ?”
Tabi tí ó sọ fún pé,
“Èmi yóo jẹ́ baba fún un,
òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?”#(a) O. Daf 2:7; (b) 2 Sam 7:14; 1Kron 17:13
6Ṣugbọn nígbà tí ó mú àkọ́bí rẹ̀ wọ inú ayé, ohun tí ó sọ ni pé,
“Kí gbogbo àwọn angẹli
Ọlọrun foríbalẹ̀ fún un.”#Diut 32:43
7Ohun tí ó sọ nípa àwọn angẹli ni pé,
“Ẹni tí ó ṣe àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀fúùfù,
tí ó ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”#O. Daf 104:4
8Ṣugbọn ohun tí ó sọ fún Ọmọ náà ni pé,
“Ìfẹ́ rẹ wà títí laelae, Ọlọrun,
ọ̀pá òtítọ́ ni ọ̀pá ìjọba rẹ.#O. Daf 45:6-7
9O fẹ́ràn òdodo, o kórìíra ẹ̀ṣẹ̀.
Nítorí èyí, Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, fi òróró yàn ọ́
láti gbé ọ ga ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”
10Ó tún sọ pé,
“O ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, Oluwa,
ìwọ ni o fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀.
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni àwọn ọ̀run.#O. Daf 102:25-27
11Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ óo wà títí.
Gbogbo wọn óo gbó bí aṣọ.
12Gẹ́gẹ́ bí eniyan tií ká aṣọ ni ìwọ óo ká wọn.
Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, a óo pààrọ̀ wọn.
Ṣugbọn ní tìrẹ, bákan náà ni o wà.
Kò sí òpin sí iye ọdún rẹ.”
13Èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé,
“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí n óo fi ṣe àwọn ọ̀tá rẹ ní àpótí ìtìsẹ̀ rẹ?”#O. Daf 110:1
14Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà.#Tob 12:14-15

Currently Selected:

HEBERU 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy