YouVersion Logo
Search Icon

ẸSIRA 1

1
Kirusi Ọba Pàṣẹ pé kí Àwọn Juu Pada
1Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Pasia, kí àsọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, OLUWA fi sí Kirusi ọba lọ́kàn láti kéde yíká gbogbo ìjọba rẹ̀ ati láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé:#Jer 25:11; 29:10
2“Èmi Kirusi, ọba Pasia kéde pé: OLUWA Ọlọrun ọ̀run ti fi gbogbo ìjọba ayé fún mi, ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda. 3Kí Ọlọrun wà pẹlu àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan rẹ̀. Ẹ lọ sí Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda, kí ẹ tún ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli kọ́, nítorí òun ni Ọlọrun tí wọn ń sìn ní Jerusalẹmu. 4Ní gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan rẹ̀ ń gbé, kí àwọn aládùúgbò wọn fi fadaka, wúrà, dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn ta wọ́n lọ́rẹ, yàtọ̀ sí ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọrun.”#Ais 44:28
5Àwọn olórí ninu ìdílé ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Bẹnjamini, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi sì dìde, pẹlu àwọn tí Ọlọrun ti fi sí lọ́kàn láti tún ilé OLUWA tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́. 6Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá.
7Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu. 8Kirusi ọba fún Mitiredati, akápò ìjọba rẹ̀ ní àṣẹ láti kó wọn síta, ó sì kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ṣeṣibasari, olórí ẹ̀yà Juda. 9Iye àwọn nǹkan náà nìyí:
Ẹgbẹrun kan (1,000) àwo wúrà,
ẹgbẹrun kan (1,000) àwo fadaka,
àwo turari mọkandinlọgbọn;
10ọgbọ̀n àwokòtò wúrà,
ẹgbaa ó lé irinwo ati mẹ́wàá (2,410) àwo fadaka kéékèèké,
ẹgbẹrun (1,000) oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn.
11Àpapọ̀ àwọn ohun èlò wúrà ati fadaka yìí jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó lé irinwo (5,400).#1:11 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn ní ẹẹdẹgbaata ó lé ọtalenirinwo (5,460), àwọn mìíràn ní ẹẹdẹgbaata ó lé ọtalenirinwo ó lé mẹsan-an (5,469) . Ṣeṣibasari kó wọn lọ́wọ́ bí àwọn tí wọn kúrò ní oko ẹrú Babiloni ti ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu.

Currently Selected:

ẸSIRA 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy