YouVersion Logo
Search Icon

DIUTARONOMI 1

1
Ìwé Karun-un Mose, tí à ń pè ní Diutaronomi
1Ọ̀rọ̀ tí Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ninu aṣálẹ̀ nìyí, ní òdìkejì odò Jọdani, ní Araba tí ó kọjú sí Sufu, láàrin Parani, Tofeli, Labani, Haserotu ati Disahabu. 2Ìrìn ọjọ́ mọkanla ni láti Horebu dé Kadeṣi Banea, tí eniyan bá gba ọ̀nà òkè Seiri. 3Ní ọjọ́ kinni oṣù kọkanla, ní ogoji ọdún tí wọ́n ti kúrò ní Ijipti, ni Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ohun tí OLUWA pàṣẹ fún un láti sọ fún wọn; 4lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni; ati Ogu, ọba àwọn ará Baṣani, tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei. 5Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn, ní ilẹ̀ Moabu, ni Mose ti ṣe àlàyé àwọn òfin wọnyi. #Nọm 21:21-35
Ó ní, 6“OLUWA Ọlọrun wa sọ fún wa ní Horebu pé, a ti pẹ́ tó ní ẹsẹ̀ òkè náà. 7Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate. 8Ó ní, ‘Ẹ wò ó! Mo ti pèsè ilẹ̀ náà fun yín, ẹ lọ, kí ẹ sì gbà á; Èmi OLUWA ti búra láti fún Abrahamu ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba ńlá yín ati arọmọdọmọ wọn.’ ”
Mose Yan Àwọn Adájọ́
(Eks 18:13-27)
9“Mo sọ fun yín nígbà náà pé, èmi nìkan kò ní lè máa ṣe àkóso yín. 10OLUWA Ọlọrun yín ti sọ yín di pupọ, lónìí ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run. 11Kí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín jẹ́ kí ẹ tún pọ̀ jù báyìí lọ lọ́nà ẹgbẹrun. Kí ó sì bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fun yín. 12Báwo ni mo ṣe lè dá nìkan dàyàkọ ìnira yín ati ẹrù yín ati ìjà yín. 13Mo ní kí ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n ní ìmọ̀ ati ìrírí láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì fi wọ́n ṣe olórí yín. 14Ìdáhùn tí ẹ fún mi nígbà náà ni pé, ohun tí mo wí ni ó yẹ kí ẹ ṣe. 15Mo bá fi mú àwọn olórí olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, àwọn tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí fun yín. Mo fi àwọn kan jẹ balogun lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn lórí araadọta eniyan; bẹ́ẹ̀ ni mo fi àwọn ẹlòmíràn jẹ balogun lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá, mo sì fi àwọn kan ṣe olórí ninu gbogbo ẹ̀yà yín.
16“Mo pàṣẹ fún àwọn adájọ́ yín nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ àwọn arakunrin yín, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo láàrin eniyan ati arakunrin rẹ̀, tabi àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 17Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́ yín; kì báà jẹ́ àwọn eniyan ńláńlá, kì báà jẹ́ àwọn mẹ̀kúnnù, bákan náà ni kí ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù eniyan, nítorí Ọlọrun ni onídàájọ́. Bí ẹjọ́ kan bá le jù fun yín láti dá, ẹ kó o tọ̀ mí wá, n óo sì dá a.’ 18Gbogbo ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe nígbà náà ni mo pa láṣẹ fun yín.
Mose Rán Àwọn Amí láti Kadeṣi Banea Lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí
(Num 13:1-33)
19“Gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wa ti pàṣẹ fún wa nígbà náà, a gbéra ní Horebu, a sì la àwọn aṣálẹ̀ ńláńlá tí wọ́n bani lẹ́rù kọjá, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe rí i ní ojú ọ̀nà àwọn agbègbè olókè àwọn ará Amori; a sì dé Kadeṣi Banea. 20Mo sọ fun yín nígbà náà pé, ẹ ti dé agbègbè olókè àwọn ará Amori, tí OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa, 21ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà.
22“Gbogbo yín wá sọ́dọ̀ mi, ẹ sì wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á rán àwọn eniyan lọ ṣiwaju wa, láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè wá jábọ̀ fún wa, kí á lè mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀, ati àwọn ìlú tí ó yẹ kí á wọ̀.’
23“Ọ̀rọ̀ yín dára lójú mi, mo sì yan ọkunrin mejila láàrin yín, ọkunrin kọ̀ọ̀kan láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. 24Wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè náà, títí tí wọ́n fi dé àfonífojì Eṣikolu, tí wọ́n sì ṣe amí rẹ̀. 25Wọ́n ká ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀, wọ́n sì jábọ̀ fún wa pé ilẹ̀ dáradára ni OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa.
26“Sibẹsibẹ, ẹ kọ̀, ẹ kò lọ, ẹ ṣe orí kunkun sí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun yín pa fun yín. 27Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kùn ninu àgọ́ yín, ẹ ní, ‘Ọlọrun kò fẹ́ràn wa, ni ó ṣe kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, kí ó lè kó wa lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa wá run. 28Kí ni a fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀? Ojora ti mú wa, nítorí ọ̀rọ̀ tí àwọn arakunrin wa sọ fún wa, tí wọ́n ní àwọn ará ibẹ̀ lágbára jù wá lọ, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ jù wá lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, odi wọn ga kan ọ̀run, àwọn òmìrán ọmọ Anaki sì wà níbẹ̀!’ #Diut 9:23; Heb 3:16
29“Mo wí fun yín nígbà náà pé kí ẹ má ṣojo, kí ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. 30OLUWA Ọlọrun yín tí ń ṣáájú yín ni yóo jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti jà fun yín ní ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i. 31Ninu aṣálẹ̀ ńkọ́? Ṣebí ẹ rí i bí OLUWA Ọlọrun yín ti gbé yín, bí baba tíí gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ tọ̀ títí tí ẹ fi dé ibi tí ẹ wà yìí. 32Sibẹsibẹ ẹ kò gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, #A. Apo 13:18 33Ọlọrun tí ń lọ níwájú yín ninu ọ̀wọ̀n iná lóru, ati ninu ìkùukùu lọ́sàn-án, láti fi ọ̀nà tí ẹ óo máa tọ̀ hàn yín kí ó lè bá yín wá ibi tí ẹ óo pàgọ́ yín sí. #Heb 3:19
OLUWA Jẹ Àwọn Ọmọ Israẹli Níyà
(Nọm 14:20-45)
34“OLUWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra pé, 35ẹnikẹ́ni ninu ìran burúkú náà kò ní fi ojú kan ilẹ̀ dáradára tí òun ti búra pé òun óo fún àwọn baba yín; 36àfi Kalebu ọmọ Jefune ni yóo rí i. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni òun óo sì fún ní ilẹ̀ tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀, nítorí pé, ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé òun. 37OLUWA bínú sí èmi pàápàá nítorí tiyín, ó ní èmi náà kò ní dé ibẹ̀. 38Joṣua, ọmọ Nuni, tí ń ṣe iranṣẹ òun, ni yóo dé ilẹ̀ náà. Nítorí náà, ó ní kí n mú un lọ́kàn le, nítorí òun ni yóo jẹ́ kí Israẹli gba ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì jogún rẹ̀. #Heb 3:18 39Ọlọrun ní àwọn ọmọ yín kéékèèké, tí kò tíì mọ ire yàtọ̀ sí ibi, àwọn tí ẹ sọ pé wọn yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín, àwọn ni wọn yóo dé ilẹ̀ náà, àwọn ni òun óo sì fi fún, ilẹ̀ náà yóo sì di ìní wọn. 40Ṣugbọn ní tiyín, ó ní kí ẹ yipada, kí ẹ sì máa lọ sinu aṣálẹ̀, ní apá ọ̀nà Òkun Pupa.
41“Nígbà náà, ẹ dá mi lóhùn, ẹ ní, ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA, nítorí náà, ẹ óo dìde, ẹ óo sì lọ jagun, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fun yín. Olukuluku yín bá múra láti jagun, gbogbo èrò yín nígbà náà ni pé kò ní ṣòro rárá láti ṣẹgun àwọn tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà.
42“OLUWA wí fún mi pé, ‘Kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má gòkè lọ jagun, nítorí pé n kò ní bá wọn lọ; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn.’ 43Mo sọ ohun tí OLUWA wí fun yín, ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́. Ẹ ṣe oríkunkun sí àṣẹ OLUWA, ẹ sì lọ pẹlu ẹ̀mí ìgbéraga. 44Àwọn ará Amori tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà bá jáde sí yín, wọ́n le yín bí oyin tíí lé ni, wọ́n sì pa yín ní ìpakúpa láti Seiri títí dé Horima. 45Nígbà tí ẹ pada dé, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí sọkún níwájú OLUWA, ṣugbọn OLUWA kò gbọ́ tiyín, bẹ́ẹ̀ ni kò fetí sí ẹkún yín.
Àkókò Tí Àwọn Ọmọ Israẹli Fi Wà ninu Aṣálẹ̀
46“Nítorí náà, gbogbo wa wà ní Kadeṣi fún ìgbà pípẹ́.

Currently Selected:

DIUTARONOMI 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy