YouVersion Logo
Search Icon

JOHANU KINNI 1

1
Ọ̀rọ̀ Ìyè
1Ohun tí ó ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, ohun tí a ti gbọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ ìyè, tí a ti fi ojú ara wa rí, tí a wò dáradára, tí a fi ọwọ́ wa dìmú, òun ni à ń sọ fun yín.#Joh 1:1 2Ìyè yìí farahàn, a ti rí i, a sì ń jẹ́rìí rẹ̀. Ìyè ainipẹkun yìí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, tí ó ti farahàn fún wa, ni a wá ń kéde fun yín.#Joh 1:14 3Ohun tí a ti rí, tí a sì ti gbọ́ ni à ń kéde fun yín, kí ẹ lè ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu wa. Ìrẹ́pọ̀ yìí ni a ní pẹlu Baba ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. 4À ń kọ àwọn nǹkan wọnyi si yín kí ayọ̀ wa lè kún.
Ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun
5Iṣẹ́ tí ó fi rán wa, tí à ń jẹ́ fun yín nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun, kò sí òkùnkùn ninu rẹ̀ rárá. 6Bí a bá wí pé a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀, tí a bá ń gbé inú òkùnkùn, òpùrọ́ ni wá, a kò sì ṣe olóòótọ́. 7Ṣugbọn bí a bá ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, bí òun náà ti wà ninu ìmọ́lẹ̀, a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọmọ rẹ̀ sì ti wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa nù kúrò lára wa.#Joh 13:34
8Bí a bá wí pé a kò lẹ́ṣẹ̀, ara wa ni à ń tàn jẹ, òtítọ́ kò sì sí ninu wa. 9Ṣugbọn bí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa: olóòótọ́ ati olódodo ni òun, yóo wẹ àìṣedéédé gbogbo nù kúrò lára wa. 10Bí a bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀ rí, a mú Ọlọrun lékèé, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí ninu wa.

Currently Selected:

JOHANU KINNI 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy