Parallel
1
Ọ̀rọ̀ Di Ènìyàn
1 # Jẹ 1.1; 1Jh 1.1; Ìf 19.13; Jh 17.5. Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà. 2Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe.
3 # Kl 1.16; 1Kọ 8.6; Hb 1.2. Nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá. 4#Jh 5.26; 11.25; 14.6.Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé, 5#Jh 9.5; 12.46.Ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀.
6 # Mk 1.4; Mt 3.1; Lk 3.3; Jh 1.19-23. Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Jòhánù. 7Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípaṣẹ̀ rẹ̀. 8Òun fúnrarẹ̀ kì í ṣe Ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún Ìmọlẹ̀ náà. 9#1Jh 2.8.Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé.
10Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n. 11Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á. 12#Ga 3.26; Jh 3.18; 1Jh 5.13.Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi agbára fún láti di ọmọ Ọlọ́run; 13#Jh 3.5; 1Pt 1.23; Jk 1.18; 1Jh 3.9.Àwọn ọmọ tí kì íṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.
14 # Ro 1.3; Ga 4.4; Fp 2.7; 1Tm 3.16; Hb 2.14; 1Jh 4.2. Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo Òun ọmọ bíbí kan ṣoṣo, àní Àyànfẹ́ rẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.
15 # Jh 1.30. Jòhánù sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ” 16#Kl 1.19; 2.9; Éf 1.23; Ro 5.21.Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún. 17#Jh 7.19.Nítorí pé nípaṣẹ̀ Mósè ni a ti fi òfin fún ni; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ ti ipaṣẹ̀ Jésù Kírísítì wá. 18#El 33.20; Jh 6.26; 1Jh 4.12; Jh 3.11.Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, ṣùgbọ́n Òun, àní Àyànfẹ́ rẹ̀ kan ṣoṣo, tí ń bẹ ní oókan àyà Baba, Òun náà ni ó fi í hàn.
Jòhánù Sọ Pé Òun Kì í Ṣe Kírísítì
19 # Jh 1.6. Èyí sì ni ẹ̀rí Jòhánù, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì láti Jérúsálẹ́mù wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe. 20#Jh 3.28.Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kírísítì náà.”
21 # Mt 11.14; 16.14; Mk 9.13; Mt 17.13; De 18.15,18. Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta há ni ìwọ? Èlíjà ni ìwọ bí?”
Ó sì wí pé, “Èmi kọ́,”
“Ìwọ ni wòlíì náà bí?”
Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
22Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀ wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”
23 # Às 40.3; Mk 1.3; Mt 3.3; Lk 3.4. Jòhánù sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Àìṣáyà fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”
24Ọ̀kan nínú àwọn Farisí tí a rán 25bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fí ń bamitíìsì nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kírísítì, tàbí Èlíjà, tàbí wòlíì náà?”
26 # Mk 1.7-8; Mt 3.11; Lk 3.16. Jòhánù dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi: ẹnìkan dúró láàárin yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀; 27Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”
28Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Bétanì ní òdì kejì odò Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣe ìtẹ̀bọmi.
Jésù Jẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ọlọ́run
29 # Jh 1.36; Às 53.7; Ap 8.32; 1Pt 1.19; Ìf 5.6; 1Jh 3.5. Ní ọjọ́ kejì Jòhánù rí Jésù tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! 30Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’ 31Èmi gan-an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Ísírẹ́lì.”
32 # Mk 1.10; Mt 3.16; Lk 3.22. Nígbà náà ni Jòhánù jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e. 33Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitíìsì sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì.’ 34Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”
Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Jésù Àkọ́kọ́
35 # Lk 7.18. Ní ọjọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jòhánù dúró, pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 36Nígbà tí ó sì rí Jésù bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”
37Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jésù lẹ́yìn. 38Nígbà náà ni Jésù yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ Òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?”
Wọ́n wí fún un pé, “Rábì” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”
39Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.”
Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.
40 # Mt 4.18-22; Mk 1.16-20; Lk 5.2-11. Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jòhánù, tí ó sì tọ Jésù lẹ́yìn. 41#Da 9.25; Jh 4.25.Ohun àkọ́kọ́ tí Ańdérù ṣe ni láti wá Símónì arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Mèṣáyà” (ẹni tí ṣe Kírísítì). 42#Jh 21.15-17; 1Kọ 15.5; Mt 16.18.Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jésù.
Jésù sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Símónì ọmọ Jónà: Kéfà ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Pétérù).
Jésù Pe Fílípì àti Nàtaníẹ́lì
43 # Mt 10.3; Jh 6.5; 12.21; 14.8. Ní ọjọ́ kéjì Jésù ń fẹ́ jáde lọ sí Gálílì, ó sì rí Fílípì, ó sì wí fún un pé, “Má a tọ̀ mí lẹ́yìn.”
44Fílípì gẹ́gẹ́ bí i Ańdérù àti Pétérù, jẹ́ ará ìlú Bẹtiṣáídà. 45#Lk 24.27.Fílípì rí Nàtaníẹ́lì, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mósè kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jésù ti Násárẹ́tì, ọmọ Jósẹ́fù.”
46 # Jh 7.41; Mk 6.2. Nàtaníẹ́lì béèrè pé, “Násárẹ́tì? Ohun rere kan há lè ti ibẹ̀ jáde?”
Fílípì wí fún un pé, “Wá wò ó.”
47Jésù rí Nàtaníẹ́lì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Ísírẹ́lì tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”
48Nàtaníẹ́lì béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?”
Jésù sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Fílípì tó pè ọ́.”
49 # Sm 2.7; Mk 15.32; Jh 12.13. Nígbà náà ni Nàtaníẹ́lì sọ ọ́ gbangba pé, “Rábì, Ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”
50Jésù sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀ jù ìwọ̀nyí lọ.” 51#Lk 3.21; Jẹ 28.12.Nígbà náà ni ó fi kún un pé, “Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn.”