Gẹn 21
BM

Gẹn 21

21
A Bí Isaaki
1OLUWA si bẹ̀ Sara wò bi o ti wi, OLUWA si ṣe fun Sara bi o ti sọ.
2Sara si loyun, o si bí ọmọkunrin kan fun Abrahamu li ogbologbo rẹ̀, li akokò igbati Ọlọrun dá fun u.
3Abrahamu si pè orukọ ọmọ rẹ̀ ti a bí fun u, ni Isaaki, ẹniti Sara bí fun u.
4Abrahamu si kọ Isaaki ọmọ rẹ̀ ni ilà, nigbati o di ọmọ ijọ́ mẹjọ, gẹgẹ bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u.
5Abrahamu si jẹ ẹni ọgọrun ọdún, nigbati a bí Isaaki ọmọ rẹ̀ fun u.
6Sara si wipe, Ọlọrun pa mi lẹrin; gbogbo ẹniti o gbọ́ yio si rẹrin pẹlu mi.
7O si wipe, Tani iba wi fun Abrahamu pe, Sara yio fi ọmú fun ọmọ mu? mo sá bí ọmọ kan fun u li ogbologbo rẹ̀.
8Ọmọ na si dàgba, a si já a li ẹnu ọmú: Abrahamu si sè àse nla li ọjọ́ na ti a já Isaaki li ẹnu ọmú.
Wọ́n Lé Hagari ati Iṣimaeli Jáde nílé
9Sara si ri ọmọ Hagari, ara Egipti, ti o bí fun Abrahamu, o nfi i rẹrin.
10Nitorina li o ṣe wi fun Abrahamu pe, Lé ẹrubirin yi jade ti on ti ọmọ rẹ̀: nitoriti ọmọ ẹrubirin yi ki yio ṣe arole pẹlu Isaaki, ọmọ mi.
11Ọrọ yi si buru gidigidi li oju Abrahamu nitori ọmọ rẹ̀.
12Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Máṣe jẹ ki o buru li oju rẹ nitori ọmọdekunrin na, ati nitori ẹrubirin rẹ; ni gbogbo eyiti Sara sọ fun ọ, fetisi ohùn rẹ̀; nitori ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ.
13Ati ọmọ ẹrubirin na pẹlu li emi o sọ di orilẹ-ède, nitori irú-ọmọ rẹ ni iṣe.
14Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o mu àkara ati ìgo omi kan, o fi fun Hagari, o gbé e lé e li ejika, ati ọmọ na, o si lé e jade: on si lọ, o nrìn kakiri ni ijù Beer-ṣeba.
15Omi na si tán ninu ìgo, o si sọ̀ ọmọ na si abẹ ìgboro kan.
16O si lọ, o joko kọju si i, li ọ̀na jijìn rére, o tó bi itafasi kan: nitori ti o wipe, Ki emi má ri ikú ọmọ na. O si joko kọju si i, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o nsọkun.
17Ọlọrun si gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na: angeli Ọlọrun si pè Hagari lati ọrun wá, o bi i pe, Kili o ṣe ọ, Hagari? máṣe bẹ̀ru; nitori ti Ọlọrun ti gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na nibiti o gbé wà.
18Dide, gbé ọmọdekunrin na, ki o si dì i mu; nitori ti emi o sọ ọ di orilẹ-ède nla.
19Ọlọrun si ṣí i li oju, o si ri kanga omi kan; o lọ, o si pọnmi kún ìgo na, o si fi fun ọmọdekunrin na mu.
20Ọlọrun si wà pẹlu ọmọdekunrin na; o si dàgba, o si joko ni ijù, o di tafatafa.
21O si joko ni ijù Parani: iya rẹ̀ si fẹ́ obinrin fun u lati ilẹ Egipti wá.
Majẹmu láàrin Abrahamu ati Abimeleki
22O si ṣe li akokò na, ni Abimeleki ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, wi fun Abrahamu pe, Ọlọrun pẹlu rẹ ni gbogbo ohun ti iwọ nṣe.
23Njẹ nisisiyi fi Ọlọrun bura fun mi nihinyi pe iwọ ki yio ṣe ẹ̀tan si mi, tabi si ọmọ mi, tabi si ọmọ-ọmọ mi: ṣugbọn gẹgẹ bi iṣeun ti mo ṣe si ọ, bẹ̃ni iwọ o si ṣe si mi, ati si ilẹ ti iwọ ti ṣe atipo ninu rẹ̀.
24Abrahamu si wipe, emi o bura.
25Abrahamu si ba Abimeleki wi nitori kanga omi kan, ti awọn ọmọ-ọdọ Abimeleki fi agbara gbà.
26Abimeleki si wipe, emi kò mọ̀ ẹniti o ṣe nkan yi: bẹ̃ni iwọ kò sọ fun mi, bẹ̃li emi kò gbọ́, bikoṣe loni.
27Abrahamu si mu agutan, ati akọmalu, o fi wọn fun Abimeleki; awọn mejeji si dá majẹmu.
28Abrahamu si yà abo ọdọ-agutan meje ninu agbo si ọ̀tọ fun ara wọn.
29Abimeleki si bi Abrahamu pe, kili a le mọ̀ abo ọdọ-agutan meje ti iwọ yà si ọ̀tọ fun ara wọn yi si?
30O si wipe, nitori abo ọdọ-agutan meje yi ni iwọ o gbà lọwọ mi, ki nwọn ki o le ṣe ẹrí mi pe, emi li o wà kanga yi.
31Nitorina li o ṣe pè ibẹ̀ na ni Beer-ṣeba; nitori nibẹ̀ li awọn mejeji gbé bura.
32Bẹ̃ni nwọn si dá majẹmu ni Beer-ṣeba: nigbana li Abimeleki dide, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilẹ awọn ara Filistia.
33Abrahamu si lọ́ igi tamariski kan ni Beer-ṣeba, nibẹ̀ li o si pè orukọ OLUWA, Ọlọrun Aiyeraiye.
34Abrahamu si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọjọ́ pupọ̀.

(C) 2012 The Bible Society of Nigeria

Learn More About Bibeli Mimọ