YouVersion Logo
Search Icon

ORIN SOLOMONI 1

1
1Àwọn orin tí ó dùn jùlọ tí Solomoni kọ nìwọ̀nyí:#1A. Ọba 4:32
Orin Kinni
Obinrin
2Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu,
nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ.
3Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn,
orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde;
nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ.
4Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá,
ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀.
Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹ
a óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ;
abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!
5Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,
mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà,
mo dàbí àgọ́ Kedari,
mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni.
6Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú,
oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀.
Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi,
wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà,
ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára.
7Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́:
níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko?
Níbo ni wọ́n ti ń sinmi,
nígbà tí oòrùn bá mú?
Kí n má baà máa wá ọ kiri,
láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ?
Ọkunrin
8Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin,
bí o kò bá mọ ibẹ̀,
ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran.
Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹko
lẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan.
9Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao.
10Nǹkan ọ̀ṣọ́ mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà,
ẹ̀gbà ọrùn sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà.
11A óo ṣe àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà,
tí a fi fadaka ṣe ọnà sí lára fún ọ.
Obinrin
12Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀,
turari mi ń tú òórùn dídùn jáde.
13Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá,
bí ó ti sùn lé mi láyà.
14Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi,
ninu ọgbà àjàrà Engedi.
Ọkunrin
15Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi;
o lẹ́wà pupọ.
Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà.
Obinrin
16Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi,
o lẹ́wà gan-an ni.
Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa.
17Igi Kedari ni òpó ilé wa,
igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa.

Currently Selected:

ORIN SOLOMONI 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy