YouVersion Logo
Search Icon

NỌMBA 1

1
Ètò Ìkànìyàn Àkọ́kọ́ láàrin Àwọn Ọmọ Israẹli
1Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé, 2“Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ìdílé-ìdílé; kí ẹ sì kọ orúkọ gbogbo àwọn ọkunrin sílẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 3Ìwọ ati Aaroni, ẹ ka gbogbo àwọn tí wọ́n lè jáde lọ sí ojú ogun, láti ẹni ogún ọdún lọ sókè. Ẹ kà wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. 4Kí ọkunrin kọ̀ọ̀kan, láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan wà pẹlu yín láti máa ràn yín lọ́wọ́. Àwọn ọkunrin tí yóo máa ràn yín lọ́wọ́ gbọdọ̀ jẹ́ baálẹ̀ ní àdúgbò wọn.” 5Orúkọ àwọn baálẹ̀-baálẹ̀ náà nìwọ̀nyí: Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Reubẹni. 6Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Simeoni. 7Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Juda. 8Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Isakari. 9Eliabu ọmọ Heloni ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Sebuluni. 10Ninu àwọn ọmọ Josẹfu, Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli ọmọ Pedasuri ni yóo sì jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Manase. 11Abidani ọmọ Gideoni ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. 12Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Dani. 13Pagieli ọmọ Okirani ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Aṣeri. 14Eliasafu ọmọ Deueli ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Gadi. 15Ahira ọmọ Enani ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Nafutali. 16Àwọn ni olórí tí a yàn ninu àwọn ọmọ Israẹli, olukuluku wọn jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn, ati ní ìdílé wọn.
17Mose ati Aaroni pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní ọjọ́ kinni oṣù keji, 18pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn ọkunrin mejila náà, wọ́n kọ orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀, láti ẹni ogún ọdún sókè, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ní ìdílé-ìdílé. 19Mose kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣálẹ̀ Sinai gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.
20Ninu ẹ̀yà Reubẹni, tíí ṣe àkọ́bí Israẹli, àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni ogún ọdún sókè, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 21jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500).
22Ninu ẹ̀yà Simeoni, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 23jẹ́ ẹgbaa mọkandinlọgbọn ó lé eedegbeje (59,300).
24Ninu ẹ̀yà Gadi, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 25jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé aadọta lé ní ẹgbẹjọ (45,650).
26Ninu ẹ̀yà Juda, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 27jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600).
28Ninu ẹ̀yà Isakari, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 29jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlọgbọn ó lé irinwo (54,400).
30Ninu ẹ̀yà Sebuluni, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 31jẹ́ ẹgbaa mejidinlọgbọn ó lé egbeje (57,400).
32Ninu ẹ̀yà Efuraimu àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 33jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).
34Ninu ẹ̀yà Manase, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 35jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun ó lé igba (32,200).
36Ninu ẹ̀yà Bẹnjamini, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 37jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogun ó lé egbeje (35,400).
38Ninu ẹ̀yà Dani, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 39jẹ́ ẹgbaa mọkanlelọgbọn ó lé ẹẹdẹgbẹrin (62,700).
40Ninu ẹ̀yà Aṣeri, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 41jẹ́ ọ̀kẹ́ meji le ẹẹdẹgbẹjọ (41,500).
42Ninu ẹ̀yà Nafutali àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé 43jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400).
44Àwọn ni àwọn tí Mose ati Aaroni kà pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí mejila tí a yàn láti inú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 45Àròpọ̀ iye àwọn ọmọ Israẹli, ní ìdílé-ìdílé, láti ẹni ogún ọdún sókè, àwọn tí wọ́n lè lọ sójú ogun, 46jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ eniyan o le egbejidinlogun ó dín aadọta (603,550). #Nọm 26:1-51
47Ṣugbọn wọn kò ka àwọn ọmọ Lefi mọ́ wọn, 48nítorí pé OLUWA ti sọ fún Mose pé, 49kí ó má ka ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí ó bá ń kà wọ́n. 50Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká. 51OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á. 52Kí àwọn ọmọ Israẹli yòókù pa àgọ́ wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, olukuluku ní ibùdó rẹ̀, lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀. 53Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi ni kí wọ́n pàgọ́ yí Àgọ́-Ẹ̀rí ká, kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ Lefi má baà súnmọ́ Àgọ́ náà, kí n má baà bínú sí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Lefi ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.” 54Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.

Currently Selected:

NỌMBA 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy