YouVersion Logo
Search Icon

JOHANU 20

20
Ajinde Jesu
(Mat 28:1-8; Mak 16:1-8; Luk 24:1-12)
1Ní kutukutu ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́, Maria Magidaleni lọ sí ibojì náà, ó rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀. 2Ó bá sáré lọ sọ́dọ̀ Simoni Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn, ó sọ fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa kúrò ninu ibojì, a kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”
3Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn náà bá jáde, wọ́n lọ sí ibojì náà. 4Àwọn mejeeji bẹ̀rẹ̀ sí sáré; ṣugbọn ọmọ-ẹ̀yìn keji ya Peteru sílẹ̀, òun ni ó kọ́ dé ibojì. 5Ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì, ó rí aṣọ-ọ̀gbọ̀ tí ó wà nílẹ̀, ṣugbọn kò wọ inú ibojì. 6Nígbà tí Simoni Peteru tí ó tẹ̀lé e dé, ó wọ inú ibojì lọ tààrà. Ó rí aṣọ-ọ̀gbọ̀ nílẹ̀, 7ó rí aṣọ tí wọ́n fi wé orí òkú lọ́tọ̀, kò sí lára aṣọ-ọ̀gbọ̀, ó dá wà níbìkan ní wíwé. 8Ọmọ-ẹ̀yìn keji tí ó kọ́kọ́ dé ẹnu ibojì náà bá wọ inú ibojì; òun náà rí i, ó wá gbàgbọ́. 9(Nítorí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí kò tíì yé wọn pé dandan ni kí ó jí dìde ninu òkú.) 10Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá tún pada lọ sí ilé wọn.
Jesu Fara Han Maria Magidaleni
(Mat 28:9-10; Mak 16:9-11)
11Ṣugbọn Maria dúró lóde lẹ́bàá ibojì, ó ń sunkún. Bí ó ti ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì, 12ó bá rí àwọn angẹli meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ọ̀kan jókòó níbi orí, ekeji jókòó níbi ẹsẹ̀ ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Jesu sí. 13Wọ́n bi í pé, “Obinrin, kí ló dé tí ò ń sunkún?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa mi lọ, n kò mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”
14Bí ó ti sọ báyìí tán, ó bojú wẹ̀yìn, ó bá rí Jesu tí ó dúró, ṣugbọn kò mọ̀ pé òun ni. 15Jesu bi í pé, “Obinrin, kí ní dé tí ò ń sunkún? Ta ni ò ń wá?”
Maria ṣebí olùṣọ́gbà ni. Ó sọ fún un pé, “Alàgbà, bí o bá ti gbé e lọ, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, kí n lè lọ gbé e.”
16Jesu bá pè é lórúkọ, ó ní, “Maria!”
Maria bá yipada sí i, ó pè é ní èdè Heberu pé, “Raboni!” (Ìtumọ̀ èyí ni “Olùkọ́ni.”)
17Jesu bá sọ fún un pé, “Mú ọwọ́ kúrò lára mi, nítorí n kò ì tíì gòkè tọ Baba mi lọ. Ṣugbọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, kí o sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín, Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’ ”
18Maria Magidaleni bá lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Mo ti rí Oluwa!” Ó bá sọ ohun tí Jesu sọ fún un fún wọn.
Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn
(Mat 28:16-20; Mak 16:14-18; Luk 24:36-49)
19Nígbà tí ó di alẹ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, níbi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà, tí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu, Jesu dé, ó dúró láàrin wọn. Ó kí wọn pé, “Alaafia fun yín!” 20Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ hàn wọ́n. 21Ó tún kí wọn pé, “Alaafia fún yín! Gẹ́gẹ́ bí baba ti rán mi níṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mo rán yín.” 22Lẹ́yìn tí ó sọ bẹ́ẹ̀ tán, ó mí sí wọn, ó bá wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́. 23Àwọn ẹni tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọlọrun dáríjì wọ́n. Àwọn ẹni tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọlọrun kò dáríjì wọ́n.”#Mat 16:19; 18:18
Tomasi Kò Kọ́kọ́ Gbàgbọ́
24Ṣugbọn Tomasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) kò sí láàrin àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí Jesu farahàn wọ́n. 25Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ fún un pé, “Àwa ti rí Oluwa!”
Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Bí n kò bá rí àpá ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀, kí n fi ìka mi kan ibi tí àpá ìṣó wọ̀n-ọn-nì wà, kí n fi ọwọ́ mi kan ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, n kò ní gbàgbọ́!”
26Lẹ́yìn ọjọ́ mẹjọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tún wà ninu ilé, Tomasi náà wà láàrin wọn. Ìlẹ̀kùn wà ní títì bẹ́ẹ̀ ni Jesu bá tún dé, ó dúró láàrin wọn, ó ní, “Alaafia fun yín!” 27Ó wá wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá, wo ọwọ́ mi, mú ọwọ́ rẹ wá kí o fi kan ẹ̀gbẹ́ mi. Má ṣe alaigbagbọ mọ́, ṣugbọn gbàgbọ́.”
28Tomasi dá a lóhùn pé, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!”
29Jesu wí fún un pé, “O wá gbàgbọ́ nítorí o rí mi! Àwọn tí ó gbàgbọ́ láì rí mi ṣe oríire!”
Èrèdí Ìwé Ìyìn Rere yìí
30Ọpọlọpọ nǹkan ati iṣẹ́ abàmì mìíràn ni Jesu ṣe lójú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí a kò kọ sinu ìwé yìí. 31Ṣugbọn a kọ ìwọ̀nyí kí ẹ lè gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun, ati pé tí ẹ bá gbàgbọ́, kí ẹ lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.

Currently Selected:

JOHANU 20: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy