YouVersion Logo
Search Icon

JEREMAYA 1

1
1Ọ̀rọ̀ Jeremaya, ọmọ Hilikaya, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí ó wà ní Anatoti, ní ilẹ̀ Bẹnjamini nìyí. 2Nígbà ayé Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda, ní ọdún kẹtala tí Josaya gun orí oyè ni OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀. 3Ó sì tún gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA ní ìgbà ayé Jehoiakimu, ọmọ Josaya, ọba Juda títí di òpin ọdún kọkanla tí Sedekaya ọmọ Josaya jọba ní ilẹ̀ Juda, títí tí ogun fi kó Jerusalẹmu ní oṣù karun-un ọdún náà.#2A. Ọba 22:3–23:27; 2Kron 34:8–35:19 #a 2A. Ọba 23:36–24:7; 2Kron 36:5-8 b 2A. Ọba 24:7,18–25:21; 2Kron 36:5-8, 11-21
Ọlọrun Pe Jeremaya
4OLUWA sọ fún mi pé,
5“Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́,
kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀,
mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.”
6Mo bá dáhùn pé,
“Háà! OLUWA Ọlọrun!
Wò ó! N kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọde ni mí.”
7Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní,
“Má pe ara rẹ ní ọmọde,
nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ.
Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ.
8Má bẹ̀rù wọn,
nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.”
9OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé,
“Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu.
10Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí,
láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀,
láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú,
láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.”
Ìran Meji
11OLUWA bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí yìí?”
Mo dáhùn, pé, “Ọ̀pá igi Alimọndi ni.”
12OLUWA bá wí fún mi pé, “Òtítọ́ ni ohun tí o rí, nítorí mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, n óo sì mú un ṣẹ.” 13OLUWA tún bi mí lẹẹkeji, ó ní, “Kí ni o rí?”
Mo bá dáhùn pé, “Mo rí ìkòkò kan tí ó ń hó lórí iná, ó tẹ̀ láti ìhà àríwá sí ìhà gúsù.”
14OLUWA bá sọ fún mi pé, “Láti ìhà àríwá ni ibi yóo ti dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà. 15Nítorí pé mò ń pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìjọba àríwá, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọba wọn yóo sì tẹ́ ìtẹ́ wọn kalẹ̀ ní ẹnubodè Jerusalẹmu, ati yíká odi gbogbo ìlú Juda. 16N óo dá wọn lẹ́jọ́ nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, tí wọn ń sun turari fún àwọn oriṣa, tí wọ́n sì ń bọ ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. 17Ṣugbọn, ìwọ dìde, di àmùrè rẹ, kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ fún wọn. Má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn ó bà ọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo dẹ́rù bà ọ́ níwájú wọn. 18Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ìlú tí a mọ odi yíká lónìí, o di òpó irin ati ògiri tí a fi bàbà mọ fún gbogbo ilẹ̀ yìí, ati fún àwọn ọba ilẹ̀ Juda, àwọn ìjòyè, ati àwọn alufaa rẹ̀, ati àwọn eniyan ilẹ̀ náà. 19Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ. Nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́ kalẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Currently Selected:

JEREMAYA 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy