YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 130

130
Adura Ẹlẹ́ṣẹ̀
1Ninu ìṣòro ńlá ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA!
2OLUWA, gbóhùn mi,
dẹtí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
3Bí OLUWA bá ń sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
ta ló lè yege?
4Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà,
kí á lè máa bẹ̀rù rẹ.
5Mo gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, àní, mo gbé ọkàn mi lé e,
mo sì ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀.
6Mò ń retí rẹ, OLUWA,
ju bí àwọn aṣọ́de ti máa ń retí kí ilẹ̀ mọ́ lọ,
àní, ju bí àwọn aṣọ́de, ti máa ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́.
7Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA!
Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà,
ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà.
8Òun óo sì ra Israẹli pada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.#Mat 1:21; Tit 2:14

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 130: YCE

Highlight

Copy

Compare

Share

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in