YouVersion Logo
Search Icon

JOHANU 14

14
Jesu Ni Ọ̀nà Dé Ọ̀dọ̀ Baba
1“Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú. Ẹ gba Ọlọrun gbọ́, kí ẹ sì gba èmi náà gbọ́. 2Yàrá pupọ ni ó wà ninu ilé Baba mi. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ n óo sọ fun yín pé mò ń lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín? 3Bí mo bá lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín, n óo tún pada wá láti mu yín lọ sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ lè wà níbi tí èmi pàápàá bá wà. 4Ẹ kúkú ti mọ ọ̀nà ibi tí mò ń lọ.”
5Tomasi wí fún un pé, “Oluwa, a kò mọ ibi tí ò ń lọ, báwo ni a ti ṣe lè mọ ọ̀nà ibẹ̀?”
6Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.#Bar 3:13-14 7Bí ẹ bá ti mọ̀ mí, ẹ óo mọ Baba mi. Láti àkókò yìí, ẹ ti mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”
8Filipi sọ fún un pé, “Oluwa, fi Baba hàn wá, èyí náà sì tó wa.”
9Jesu wí fún un pé, “Bí mo ti pẹ́ lọ́dọ̀ yín tó yìí, sibẹ ìwọ kò mọ̀ mí, Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi ti rí Baba. Kí ló dé tí o fi tún ń sọ pé, ‘Fi Baba hàn wá?’ 10Àbí o kò gbàgbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi ni? Èmi fúnra mi kọ́ ni mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fun yín. Baba tí ó ń gbé inú mi ni ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 11Ẹ gbà mí gbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí iṣẹ́ wọnyi. 12Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ yóo ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; yóo tilẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ju ìwọ̀nyí lọ, nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba. 13Èmi yóo ṣe ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi, kí ògo Baba lè yọ lára Ọmọ. 14Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ mi#14:14 Kò sí lọ́wọ́ mi ninu àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn . ní orúkọ mi, èmi yóo ṣe é.
Jesu Ṣèlérí pé Ẹ̀mí Mímọ́ yóo Wá
15“Bí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ óo pa òfin mi mọ́.#Ọgb 6:18 16N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae. 17Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín.
18“Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ bí aláìlárá. Mò ń pada bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. 19Láìpẹ́, ayé kò ní rí mi mọ́, ṣugbọn ẹ̀yin yóo rí mi. Nítorí èmi wà láàyè, ẹ̀yin náà yóo wà láàyè. 20Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin yóo mọ̀ pé èmi wà ninu Baba mi, ati pé ẹ̀yin wà ninu mi, èmi náà sì wà ninu yín.
21“Ẹni tí ó bá gba òfin mi, tí ó sì pa wọ́n mọ́, òun ni ó fẹ́ràn mi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn mi, Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi náà yóo fẹ́ràn rẹ̀, n óo sì fi ara mi hàn án.”#Ọgb 6:12, 18; Sir 4:14
22Judasi keji, (kì í ṣe Judasi Iskariotu), bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí o ṣe wí pé o kò ní fi ara rẹ han aráyé, ṣugbọn àwa ni ìwọ óo fi ara hàn?”
23Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé. 24Ẹni tí kò bá fẹ́ràn mi kò ní tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Ọ̀rọ̀ tí ẹ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni.
25“Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ yín. 26Ṣugbọn Alátìlẹ́yìn náà, Ẹ̀mí Mímọ́ tí Baba yóo rán wá ní orúkọ mi, ni yóo kọ yín, tí yóo sì ran yín létí ohun gbogbo tí mo sọ fun yín.
27“Alaafia ni mo fi sílẹ̀ fun yín. Alaafia mi ni mo fun yín. Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ni mo fun yín. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín. 28Ẹ gbọ́ nígbà tí mo sọ fun yín pé, ‘Mò ń lọ, ṣugbọn n óo tún pada wá sọ́dọ̀ yín.’ Bí ẹ bá fẹ́ràn mi ni, yíyọ̀ ni ẹ̀ bá máa yọ̀ pé, mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba jù mí lọ. 29Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́ nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán. 30N kò tún ní ohun pupọ ba yín sọ mọ́, nítorí aláṣẹ ayé yìí ń bọ̀. Kò ní agbára kan lórí mi. 31Ṣugbọn kí ayé lè mọ̀ pé mo fẹ́ràn Baba ni mo ṣe ń ṣe bí Baba ti pàṣẹ fún mi.
“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á kúrò níhìn-ín.

Currently Selected:

JOHANU 14: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy