YouVersion Logo
Search Icon

JẸNẸSISI 35

35
Ọlọrun Súre fún Jakọbu ní Bẹtẹli
1Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún Jakọbu pé, “Dìde, lọ sí Bẹtẹli kí o máa gbé ibẹ̀, kí o tẹ́ pẹpẹ kan fún Ọlọrun tí ó farahàn ọ́ nígbà tí ò ń sálọ fún Esau, arakunrin rẹ.”#Jẹn 28:11-17.
2Jakọbu bá sọ fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ ati àwọn alábàágbé rẹ̀, pé, “Ẹ kó gbogbo ère oriṣa tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín dànù, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. 3Lẹ́yìn náà ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtẹli, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún Ọlọrun, ẹni tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, tí ó sì wà pẹlu mi ní gbogbo ibi tí mo ti lọ.” 4Gbogbo wọn bá dá àwọn ère oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn jọ fún Jakọbu, ati gbogbo yẹtí tí ó wà ní etí wọn, Jakọbu bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ lábẹ́ igi oaku tí ó wà ní Ṣekemu.
5Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sì dà bo gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká wọn, wọn kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu. 6Jakọbu ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá wá sí Lusi, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí nnì ni Bẹtẹli. 7Ó tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ, ó sì sọ ibẹ̀ ní Eli-Bẹtẹli, nítorí pé níbẹ̀ ni Ọlọrun ti farahàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arakunrin rẹ̀. 8Níbẹ̀ ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú sí, wọ́n sì sin ín sí abẹ́ igi oaku kan ní ìhà gúsù Bẹtẹli, Jakọbu bá sọ ibẹ̀ ní Aloni-bakuti.
9Ọlọrun tún fara han Jakọbu, nígbà tí ó jáde kúrò ní Padani-aramu, ó súre fún un. 10Ọlọrun wí fún un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ, ṣugbọn wọn kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe sọ ọ́ ní Israẹli.#Jẹn 32:28 11Ọlọrun tún sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa bímọ lémọ, kí o sì pọ̀ sí i, ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati ọpọlọpọ ọba ni yóo ti ara rẹ jáde. 12N óo fún ọ ní ilẹ̀ tí mo fún Abrahamu ati Isaaki, àwọn ọmọ rẹ ni yóo sì jogún rẹ̀.”#Jẹn 17:4-8 13Ọlọrun bá gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti bá a sọ̀rọ̀. 14Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n òkúta kan nàró níbẹ̀, ó fi ohun mímu rúbọ lórí òkúta náà, ó ta òróró sórí rẹ̀, 15Ó sì sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli.#Jẹn 28:18-19
Ikú Rakẹli
16Wọ́n kúrò ní Bẹtẹli, nígbà tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n dé Efurati ni ọmọ mú Rakẹli, ara sì ni ín gidigidi. 17Bí ó ti ń rọbí lọ́wọ́, agbẹ̀bí tí ń gbẹ̀bí rẹ̀ ń dá a lọ́kàn le pé, “Má bẹ̀rù, ọkunrin ni o óo tún bí.” 18Nígbà tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bọ́ lọ, kí ó tó kú, ó sọ ọmọ náà ní Benoni, ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ́ ní Bẹnjamini.
19Bẹ́ẹ̀ ni Rakẹli ṣe kú, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà Efurati, èyí nnì ni Bẹtilẹhẹmu. 20Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n kan nàró lórí ibojì rẹ̀, òun ni wọ́n ń pè ní ọ̀wọ̀n ibojì Rakẹli, ó sì wà níbẹ̀ títí di òní. 21Jakọbu tún bẹ̀rẹ̀ sí bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó pàgọ́ rẹ̀ sí òdìkejì ilé ìṣọ́ Ederi.
Àwọn Ọmọ Jakọbu
(1Kron 2:1-2)
22Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀.#Jẹn 49:4
23Àwọn ọmọ Jakọbu jẹ́ mejila. Àwọn tí Lea bí ni: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu. Lẹ́hìn rẹ̀ ni ó bí Simeoni, Lefi, Juda, Isakari ati Sebuluni. 24Àwọn tí Rakẹli bí ni: Josẹfu ati Bẹnjamini. 25Àwọn tí Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli bí ni: Dani ati Nafutali. 26Àwọn tí Silipa, iranṣẹbinrin Lea bí ni: Gadi ati Aṣeri. Àwọn wọnyi ni àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún Jakọbu ní Padani-aramu.
Ikú Isaaki
27Jakọbu pada sọ́dọ̀ Isaaki, baba rẹ̀, ní Mamure, ìlú yìí kan náà ni wọ́n ń pè ní Kiriati Ariba tabi Heburoni, níbi tí Abrahamu ati Isaaki gbé. 28Isaaki jẹ́ ẹni ọgọsan-an (180) ọdún nígbà tí ó kú. 29Ó dàgbà, ó darúgbó lọpọlọpọ kí ó tó kú. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Esau ati Jakọbu, sì sin ín.#Jẹn 28:9.

Currently Selected:

JẸNẸSISI 35: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy