JẸNẸSISI 32
BM
32
Jakọbu Múra láti Pàdé Esau
1Bí Jakọbu ti ń lọ ní ojú ọ̀nà, àwọn angẹli Ọlọrun pàdé rẹ̀. 2Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó ní, “Àwọn ọmọ ogun Ọlọrun nìyí.” Ó bá sọ ibẹ̀ ní Mahanaimu.
3Jakọbu rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Esau, ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Seiri, ní agbègbè Edomu. 4Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí ẹ óo sọ fún Esau, oluwa mi nìyí, ẹ ní èmi, Jakọbu iranṣẹ rẹ̀, ní kí ẹ sọ fún un pé mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani, ati pé ibẹ̀ ni mo sì ti wà títí di àkókò yìí. 5Ẹ ní mo ní àwọn mààlúù, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, agbo ẹran, àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin. Ẹ ní mo ní kí n kọ́ ranṣẹ láti sọ fún un ni, kí n lè rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ̀.”
6Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà pada wá jábọ̀ fún Jakọbu, wọ́n sọ fún un pé, “A jíṣẹ́ rẹ fún Esau arakunrin rẹ, ó sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ pẹlu irinwo (400) ọkunrin.” 7Ẹ̀rù ba Jakọbu gidigidi, ó sì dààmú, ó bá dá àwọn eniyan tí wọn wà pẹlu rẹ̀ ati agbo mààlúù, ati agbo aguntan ati àwọn ràkúnmí rẹ̀ sí ọ̀nà meji meji. 8Ó rò ninu ara rẹ̀ pé bí Esau bá dé ọ̀dọ̀ ìpín tí ó wà níwájú, tí ó bá sì pa wọ́n run, ìpín kan tí ó kù yóo sá àsálà.
9Jakọbu bá gbadura báyìí pé, “Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, Ọlọrun tí ó wí fún mi pé, ‘Pada sí ilẹ̀ rẹ ati sí ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, n óo sì ṣe ọ́ níre.’ 10N kò lẹ́tọ̀ọ́ sí èyí tí ó kéré jùlọ ninu ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀, ati òdodo tí o ti fihan èmi iranṣẹ rẹ, nítorí ọ̀pá lásán ni mo mú lọ́wọ́ nígbà tí mo gòkè odò Jọdani, ṣugbọn nisinsinyii, mo ti di ẹgbẹ́ ogun ńlá meji. 11Mo bẹ̀ ọ́, gbà mí lọ́wọ́ Esau arakunrin mi, nítorí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, kí ó má baà wá pa gbogbo wa, àtàwọn ìyá, àtàwọn ọmọ wọn. 12Ìwọ ni o ṣá sọ fún mi pé, ‘Ire ni n óo ṣe fún ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí iyanrìn etí òkun tí ẹnikẹ́ni kò ní lè kà tán.’ ”#Jẹn 22:17
13Ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì mú ninu ohun ìní rẹ̀ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún Esau arakunrin rẹ̀. 14Ó ṣa igba (200) ewúrẹ́ ati ogún òbúkọ, igba (200) aguntan, ati ogún àgbò, 15ọgbọ̀n abo ràkúnmí, tàwọn tọmọ wọn, ogoji abo mààlúù ati akọ mààlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati akọ mẹ́wàá. 16Ó fi iranṣẹ kọ̀ọ̀kan ṣe olùtọ́jú agbo ẹran kọ̀ọ̀kan. Ó sọ fún àwọn iranṣẹ wọnyi pé, “Ẹ máa lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrin agbo ẹran kan ati ekeji.” 17Ó sọ fún èyí tí ó ṣáájú patapata pé, “Nígbà tí Esau arakunrin mi bá pàdé rẹ, tí ó sì bi ọ́ pé, ‘Ti ta ni ìwọ í ṣe? Níbo ni ò ń lọ? Ta ló sì ni àwọn ẹran tí wọ́n wà níwájú rẹ?’ 18Kí o wí pé, ‘Ti Jakọbu iranṣẹ rẹ ni, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn tí ó fi ranṣẹ sí Esau oluwa rẹ̀, òun alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ” 19Bákan náà ni ó kọ́ ekeji ati ẹkẹta ati gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n tẹ̀lé àwọn agbo ẹran náà. Ó ní, “Nǹkan kan náà ni kí ẹ máa wí fún Esau, nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀. 20Kí ẹ sì wí pé, ‘Jakọbu alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ” Nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, bóyá òun lè fi àwọn ẹ̀bùn tí ó tì ṣáájú wọnyi tù ú lójú, àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, nígbà tí ojú àwọn mejeeji bá pàdé, bóyá yóo dáríjì òun. 21Nítorí náà, àwọn ẹ̀bùn ni ó kọ́ lọ ṣáájú rẹ̀, òun pàápàá sì dúró ninu àgọ́ ní alẹ́ ọjọ́ náà.
Jakọbu jìjàkadì ní Penieli
22Ní òru ọjọ́ náà gan an, ó dìde ó kó àwọn aya rẹ̀ mejeeji, àwọn iranṣẹbinrin mejeeji ati àwọn ọmọ rẹ̀ mọkọọkanla, ó kọjá sí ìhà keji odò Jaboku. 23Ó kó àwọn ati ohun gbogbo tí ó ní kọjá sí ìhà keji odò.#Ọgb 10:12 24Ó wá ku Jakọbu nìkan, ọkunrin kan bá a wọ ìjàkadì títí di àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ keji. 25Nígbà tí ọkunrin náà rí i pé òun kò lè dá Jakọbu, ó fi ọwọ́ kan kòtò itan rẹ̀, eegun itan Jakọbu bá yẹ̀ níbi tí ó ti ń bá a jìjàkadì. 26Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí n lọ nítorí ilẹ̀ ti ń mọ́” Ṣugbọn Jakọbu kọ̀, ó ní, “N kò ní jẹ́ kí o lọ, àfi bí o bá súre fún mi.”#Hos 12:3-4
27Ọkunrin náà bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Jakọbu dáhùn pé, “Jakọbu ni.”
28Ọkunrin náà bá dáhùn pé, “A kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni a óo máa pè ọ́, nítorí pé o ti bá Ọlọrun ati eniyan wọ ìjàkadì, o sì ti ṣẹgun.”#Jẹn 35:10
29Jakọbu bá bẹ̀ ẹ́, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣugbọn ó dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí o fi ń bèèrè orúkọ mi?” Ó bá súre fún Jakọbu níbẹ̀.#A. Ada 13:17-18
30Nítorí náà ni Jakọbu fi sọ ibẹ̀ ní Penieli, ó ní, “Mo ti rí Ọlọrun lojukooju, sibẹ mo ṣì wà láàyè.” 31Oòrùn yọ kí ó tó kọjá Penueli, nítorí pé títiro ni ó ń tiro lọ nítorí itan rẹ̀. 32Nítorí náà, títí di òní, àwọn ọmọ Israẹli kì í jẹ iṣan tí ó bo ihò itan níbi tí itan ti sopọ̀ mọ́ ìbàdí, nítorí pé ihò itan Jakọbu ni ọkunrin náà fọwọ́ kàn, orí iṣan tí ó so ó pọ̀ mọ́ ìbàdí.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Learn More About Yoruba Bible