JẸNẸSISI 30
BM
30
1Nígbà tí Rakẹli rí i pé òun kò bímọ fún Jakọbu rárá, ó bẹ̀rẹ̀ sí jowú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó wí fún Jakọbu pé, “Tí o kò bá fẹ́ kí n kú sí ọ lọ́rùn, fún mi lọ́mọ.”
2Inú bí Jakọbu pupọ sí ọ̀rọ̀ tí Rakẹli sọ, ó dá a lóhùn pé, “Ṣé èmi ni Ọlọrun tí kò fún ọ lọ́mọ ni?”
3Rakẹli bá dáhùn, ó ní, “Biliha, iranṣẹbinrin mi nìyí, bá a lòpọ̀, kí ó bímọ sí mi lọ́wọ́, kí èmi náà sì lè ti ipa rẹ̀ di ọlọ́mọ.” 4Ó bá fún Jakọbu ní Biliha, iranṣẹbinrin rẹ̀ kí ó fi ṣe aya, Jakọbu sì bá a lòpọ̀. 5Biliha lóyún, ó bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu. 6Rakẹli bá sọ pé, “Ọlọrun dá mi láre, ó gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ní ọmọkunrin kan.” Nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Dani. 7Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli tún lóyún, ó bí ọmọkunrin keji fún Jakọbu. 8Rakẹli bá sọ pé, “Ìjàkadì gidi ni mo bá ẹ̀gbọ́n mi jà, mo sì ṣẹgun,” ó sì sọ ọmọ náà ní Nafutali.
9Nígbà tí Lea rí i pé òun kò bímọ mọ́, ó fún Jakọbu ní Silipa, iranṣẹbinrin rẹ̀, kí ó fi ṣe aya. 10Iranṣẹbinrin Lea bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu. 11Lea bá sọ pé, “Oríire.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Gadi. 12Iranṣẹbinrin Lea tún bí ọmọkunrin mìíràn fún Jakọbu. 13Lea bá ní, “Mo láyọ̀, nítorí pé àwọn obinrin yóo máa pè mí ní Ẹni-Ayọ̀,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Aṣeri.
14Ní àkókò ìkórè ọkà alikama, Reubẹni bá wọn lọ sí oko, ó sì já èso mandiraki bọ̀ fún Lea ìyá rẹ̀. Nígbà tí Rakẹli rí i, ó bẹ Lea pé kí ó fún òun ninu èso mandiraki ọmọ rẹ̀. 15Ṣugbọn Lea dá a lóhùn pé, “O gba ọkọ mọ́ mi lọ́wọ́, kò tó ọ, o tún fẹ́ gba èso mandiraki ọmọ mi lọ́wọ́ mi?” Rakẹli bá dá a lóhùn, ó ní: “Bí o bá fún mi ninu èso mandiraki ọmọ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni Jakọbu yóo sùn lálẹ́ òní.”
16Ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí Jakọbu ti oko dé, Lea jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni o gbọdọ̀ sùn ní alẹ́ òní, èso mandiraki ọmọ mi ni mo fi san owó ọ̀yà rẹ. Jakọbu bá sùn lọ́dọ̀ rẹ̀ di ọjọ́ keji.”
17Ọlọrun gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Lea, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin karun-un. 18Lea ní “Ọlọrun san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo fún ọkọ mi ní iranṣẹbinrin mi.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Isakari. 19Lea tún lóyún, ó bí ọkunrin kẹfa. 20Ó ní, “Ọlọrun ti fi ẹ̀bùn rere fún mi, nígbà yìí ni ọkọ mi yóo tó bu ọlá fún mi, nítorí pé mo bí ọkunrin mẹfa fún un,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Sebuluni. 21Lẹ́yìn náà, ó bí obinrin kan, ó sọ ọ́ ní Dina.
22Lẹ́yìn náà ni Ọlọrun ranti Rakẹli, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣí inú rẹ̀. 23Rakẹli lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. 24Ó wí pé, “Ọlọrun ti mú ẹ̀gàn mi kúrò,” ó sọ ọmọ náà ní Josẹfu; ó ní, “Kí OLUWA má ṣàì fún mi ní ọmọkunrin mìíràn.”
Jakọbu Dúnàá Dúrà pẹlu Labani
25Lẹ́yìn tí Rakẹli bí Josẹfu, Jakọbu tọ Labani lọ, ó bẹ̀ ẹ́ pé “Jẹ́ kí n pada sí ilé mi. 26Jẹ́ kí àwọn aya ati àwọn ọmọ mi máa bá mi lọ, nítorí wọn ni mo ṣe sìn ọ́. Jẹ́ kí n máa lọ, ìwọ náà ṣá mọ̀ bí mo ti sìn ọ́ tó.”
27Ṣugbọn Labani dá a lóhùn pé, “Gbà mí láàyè kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí, mo ti ṣe àyẹ̀wò, mo sì ti rí i pé nítorí tìrẹ ni OLUWA ṣe bukun mi, 28sọ iye tí o bá fẹ́ máa gbà, n óo sì máa san án fún ọ.”
29Jakọbu bá dáhùn pé, “Ìwọ náà mọ̀ bí mo ti sìn ọ́ ati bí àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ ti ṣe dáradára lọ́wọ́ mi. 30Ẹran ọ̀sìn díẹ̀ ni o ní kí n tó dé ọ̀dọ̀ rẹ, díẹ̀ náà ti di pupọ nisinsinyii OLUWA ti bukun ọ ní gbogbo ọ̀nà nítorí tèmi. Nígbà wo ni èmi gan-an yóo tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkójọ àwọn ohun tí mo lè pè ní tèmi?”
31Labani bá bi í léèrè pé, “Kí ni kí n máa fún ọ?” Jakọbu dáhùn pé, “Má fún mi ní ohunkohun, bí o bá gbà láti ṣe ohun kan fún mi, n óo tún máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ. 32Jẹ́ kí n bọ́ sí ààrin àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ lónìí, kí n sì ṣa gbogbo ọmọ aguntan dúdú, ati gbogbo ọmọ ewúrẹ́ ati aguntan tí ó ní dúdú tóótòòtóó lára, tí ó dàbí adíkálà, irú àwọn ẹran wọnyi ni n óo máa gbà fún iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún ọ. 33Bẹ́ẹ̀ ni òdodo mi yóo jẹ́rìí gbè mí ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí o bá wá wo ọ̀yà mi. Èyíkéyìí tí kò bá jẹ́ dúdú ninu àwọn aguntan, tabi ewúrẹ́ tí àwọ̀ rẹ̀ kò bá ní dúdú tóótòòtóó tí o bá rí láàrin àwọn ẹran mi, a jẹ́ pé mo jí i gbé ni.”
34Labani bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, ohun tí o wí gan-an ni a óo ṣe.” 35Ṣugbọn ní ọjọ́ náà gan-an ni Labani ṣa gbogbo ewúrẹ́ ati òbúkọ tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó, tabi tí ó dàbí adíkálà, ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní funfun lára, ati gbogbo àwọn aguntan dúdú, ó kó wọn lé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. 36Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá kó wọn lọ jìnnà sí Jakọbu, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta. Jakọbu bá ń tọ́jú agbo ẹran Labani tí ó kù.
37Jakọbu gé ọ̀pá igi populari ati ti alimọndi, ati ti pilani tútù, ó bó àwọn ọ̀pá náà ní àbófín, ó jẹ́ kí funfun wọn hàn síta. 38Ó to àwọn ọ̀pá wọnyi siwaju àwọn ẹran níbi tí wọ́n ti ń mu omi, nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá wá mu omi ni wọ́n máa ń gùn. 39Àwọn ẹran náà ń gun ara wọn níwájú àwọn ọ̀pá wọnyi, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà ati àwọn tí wọ́n ní funfun tóótòòtóó.
40Jakọbu ṣa àwọn ọmọ aguntan wọnyi sọ́tọ̀, ó sì tún mú kí gbogbo agbo ẹran Labani dojú kọ àwọn ẹran tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó tabi tí ó dàbí adíkálà, tabi àwọn tí wọ́n jẹ́ dúdú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣa àwọn ẹran tirẹ̀ sinu agbo kan lọ́tọ̀, kò pa wọ́n pọ̀ pẹlu ti Labani.
41Nígbà tí àwọn ẹran tí ara wọ́n le dáradára láàrin agbo bá ń gùn, Jakọbu a fi àwọn ọ̀pá náà siwaju wọn, kí wọ́n lè máa gùn láàrin wọn. 42Ṣugbọn nígbà tí àwọn ẹran tí kò lókun ninu tóbẹ́ẹ̀ bá ń gùn, kì í fi àwọn ọ̀pá náà siwaju wọn, báyìí ni àwọn ẹran tí kò lókun ninu di ti Labani, àwọn tí wọ́n lókun ninu sì di ti Jakọbu. 43Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu ṣe di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ó sì ní àwọn agbo ẹran ńláńlá, ọpọlọpọ iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin, ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Learn More About Yoruba Bible