YouVersion Logo
Search Icon

JẸNẸSISI 20

20
Abrahamu ati Abimeleki
1Láti ibẹ̀ ni Abrahamu ti lọ sí agbègbè Nẹgẹbu, ó sì ń gbé Gerari, ní ààrin Kadeṣi ati Ṣuri. 2Abrahamu sọ fún àwọn ará Gerari pé arabinrin òun ni Sara aya rẹ̀, Abimeleki, ọba Gerari bá ranṣẹ lọ mú Sara.#Jẹn 12:13; 26:7 3Ṣugbọn Ọlọrun tọ Abimeleki wá lóru lójú àlá, ó sì wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀! Ikú ti pa ọ́ tán báyìí, nítorí pé obinrin tí o mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.”
4Ṣugbọn Abimeleki kò tíì bá Sara lòpọ̀ rárá, ó bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, o wá lè pa àwọn eniyan aláìṣẹ̀ bí? 5Ṣebí ẹnu ara rẹ̀ ni ó fi sọ pé arabinrin òun ni, tí obinrin náà sì sọ pé arakunrin òun ni. Ohun tí mo ṣe tí ó di ẹ̀ṣẹ̀ yìí, òtítọ́ inú ati àìmọ̀ ni mo fi ṣe é.”
6Ọlọrun dá a lóhùn lójú àlá, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé òtítọ́ inú ni o fi ṣe ohun tí o ṣe, èmi ni mo sì pa ọ́ mọ́ tí n kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ mí, ìdí sì nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án. 7Ǹjẹ́ nisinsinyii, dá obinrin náà pada fún ọkọ rẹ̀, nítorí pé wolii ni ọkunrin náà yóo gbadura fún ọ, o óo sì yè. Ṣugbọn bí o kò bá dá a pada, mọ̀ dájú pé o óo kú, àtìwọ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ.”
8Abimeleki yára dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ jọ, ó ro gbogbo nǹkan wọnyi fún wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 9Abimeleki bá pe Abrahamu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí o fi ti ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí sí èmi ati ìjọba mi lọ́rùn? Ohun tí o ṣe sí mi yìí kò dára rárá!” 10Ó bi Abrahamu pé, “Kí ni èrò rẹ gan-an, tí o fi ṣe ohun tí o ṣe yìí?”
11Abrahamu dáhùn, ó ní, “Ohun tí ó mú mi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, mo rò pé kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun níhìn-ín rárá ni, ati pé wọn yóo tìtorí aya mi pa mí. 12Ati pé, arabinrin mi ni nítòótọ́, bí ó ṣe jẹ́ nìyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìyá kan náà ni ó bí wa, ọmọ baba kan ni wá kí ó tó di aya mi. 13Nígbà tí Ọlọrun mú kí n máa káàkiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Oore kan tí o lè ṣe fún mi nìyí: níbi gbogbo tí a bá dé, wí fún wọn pé, arakunrin rẹ ni mí.’ ”
14Abimeleki mú aguntan ati mààlúù ati ẹrukunrin ati ẹrubinrin, ó kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara, aya rẹ̀, pada fún un. 15Abimeleki tún wí fún un pé, “Wo gbogbo ilẹ̀ yìí, èmi ni mo ni ín, yan ibi tí ó bá wù ọ́ láti gbé.” 16Ó wí fún Sara náà pé, “Mo ti kó ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka fún arakunrin rẹ, èyí ni láti wẹ̀ ọ́ mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ, nisinsinyii, o ti gba ìdáláre lójú gbogbo eniyan.”
17Abrahamu bá gbadura sí Ọlọrun, Ọlọrun sì wo Abimeleki sàn ati aya rẹ̀ ati àwọn ẹrubinrin rẹ̀, tí wọ́n fi lè bímọ, 18nítorí pé Ọlọrun ti sé gbogbo àwọn obinrin ilé Abimeleki ninu nítorí Sara, aya Abrahamu.

Currently Selected:

JẸNẸSISI 20: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy