JẸNẸSISI 18
BM

JẸNẸSISI 18

18
Ọlọrun Ṣèlérí Ọmọkunrin Kan fún Abrahamu
1Ní ọ̀sán gangan ọjọ́ kan, OLUWA fara han Abrahamu bí ó ti jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, lẹ́bàá igi Oaku ti Mamure. 2Bí ó ti gbójú sókè, bẹ́ẹ̀ ni ó rí àwọn ọkunrin mẹta kan, wọ́n dúró ní ọ̀kánkán níwájú rẹ̀. Bí ó ti rí wọn, ó sáré lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn.#Heb 13:2 3Ó wí pé, “Ẹ̀yin oluwa mi, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má kọjá lọ bẹ́ẹ̀ láìdúró díẹ̀ lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín! 4Ẹ jẹ́ kí wọ́n bu omi wá kí ẹ fi ṣan ẹsẹ̀, kí ẹ sì sinmi díẹ̀ lábẹ́ igi níhìn-ín. 5Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti yà lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín, ẹ kúkú jẹ́ kí n tètè tọ́jú oúnjẹ díẹ̀ fún yín láti jẹ, bí ẹ bá tilẹ̀ wá fẹ́ máa lọ nígbà náà, kò burú.”
Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, lọ ṣe bí o ti wí.”
6Abrahamu yára wọ inú àgọ́ tọ Sara lọ, ó sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ tètè tọ́jú ìwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹta, bá mi yára pò ó, kí o fi ṣe àkàrà.” 7Abrahamu tún yára lọ sinu agbo mààlúù rẹ̀, ó mú ọ̀dọ́ mààlúù kan tí ó lọ́ràá dáradára, ó fà á fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó ní kí wọ́n yára pa á, kí wọ́n sì sè é. 8Ó mú wàràǹkàṣì, ati omi wàrà, ati ẹran ọ̀dọ́ mààlúù tí wọ́n sè, ó gbé wọn kalẹ̀ fún àwọn àlejò náà, ó sì dúró tì wọ́n bí wọ́n ti ń jẹun lábẹ́ igi.
9Nígbà tí wọ́n jẹun tán, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Sara aya rẹ wà?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ninu àgọ́.”
10Ọ̀kan ninu àwọn àlejò náà wí pé, “Dájúdájú, n óo pada tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara, aya rẹ yóo bí ọmọkunrin kan.”
Sara fetí mọ́ ògiri lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ lẹ́yìn ibi tí àwọn àlejò náà wà, ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ.#Heb 9:9. 11Abrahamu ati Sara ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó ti dé sí wọn, ọjọ́ ti pẹ́ tí Sara ti rí nǹkan oṣù rẹ̀ kẹ́yìn. 12Nítorí náà, nígbà tí Sara gbọ́ pé òun óo bímọ, ó rẹ́rìn-ín sinu ara rẹ̀, ó ní, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó, tí ọkọ mi náà sì ti di arúgbó, ǹjẹ́ mo tilẹ̀ tún lè gbádùn oorun ọmọ bíbí?”#1 Pet 3:6.
13OLUWA bi Abrahamu pé, “Èéṣe tí Sara fi rẹ́rìn-ín, tí ó wí pé, ṣé lóòótọ́ ni òun óo bímọ lẹ́yìn tí òun ti darúgbó? 14Ṣé ohun kan wà tí ó ṣòro fún OLUWA ni? Nígbà tí àkókò bá tó, n óo pada wá sọ́dọ̀ rẹ níwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara yóo bí ọmọkunrin kan.”#Luk 1:37.
15Ẹ̀rù ba Sara, ó sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. OLUWA sọ pé, “Má purọ́! o rẹ́rìn-ín.”
Abrahamu Bẹ̀bẹ̀ fún Sodomu
16Nígbà tí àwọn ọkunrin náà kúrò lọ́dọ̀ Abrahamu, wọ́n dojú kọ ọ̀nà Sodomu, Abrahamu bá wọn lọ láti sìn wọ́n dé ọ̀nà. 17OLUWA sọ pé, “Mo ha gbọdọ̀ fi ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí pamọ́ fún Abrahamu, 18nígbà tí ó jẹ́ pé ìran rẹ̀ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá tí yóo lágbára, ati pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè? 19N kò ní fi pamọ́ fún un, nítorí pé mo ti yàn án, kí ó lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo ará ilé rẹ̀, láti máa pa ìlànà èmi OLUWA mọ́, ati kí wọ́n sì jẹ́ olódodo ati olóòótọ́, kí èmi OLUWA lè mú ìlérí mi ṣẹ fún Abrahamu.”
20OLUWA bá sọ pé; “Ẹ̀sùn tí àwọn eniyan fi ń kan Sodomu ati Gomora ti pọ̀ jù, ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jáì! 21Mo fẹ́ lọ fi ojú ara mi rí i, kí n fi mọ̀, bóyá gbogbo bí mo ti ń gbọ́ nípa wọn ni wọ́n ń ṣe nítòótọ́.”
22Àwọn ọkunrin náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà Sodomu lọ, ṣugbọn Abrahamu tún dúró níwájú OLUWA níbẹ̀. 23Abrahamu bá súnmọ́ OLUWA, ó wí pé, “O ha gbọdọ̀ pa àwọn olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú bí? 24A kì í bàá mọ̀, bí aadọta olódodo bá wà ninu ìlú náà, ṣé o óo pa ìlú náà run, o kò sì ní dá a sí nítorí aadọta olódodo tí ó wà ninu rẹ̀? 25Kí á má rí i pé o ṣe irú ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀! Kí o pa olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú? Ṣé kò ní sí ìyàtọ̀ láàrin ìpín àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn olódodo ni? A kò gbọdọ̀ gbọ́ ọ. Ìwọ onídàájọ́ gbogbo ayé kò ha ní ṣe ẹ̀tọ́ bí?”
26OLUWA dáhùn, ó ní, “Bí mo bá rí aadọta olódodo ninu ìlú Sodomu, n óo dá gbogbo ìlú náà sí nítorí tiwọn.”
27Abrahamu tún sọ fún OLUWA pé, “Jọ̀wọ́, dárí àfojúdi mi jì mí, èmi eniyan lásán, nítorí n kò ní ẹ̀tọ́ láti bá ìwọ OLUWA jiyàn? 28Ṣugbọn, ó ṣeéṣe pé aadọta tí mo wí lè dín marun-un, ṣé nítorí eniyan marun-un tí ó dín, o óo pa ìlú náà run?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí olódodo marundinlaadọta n kò ní pa ìlú náà run.”
29Ó tún bèèrè pé, “Bí a bá rí ogoji ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn, ó ní, “N kò ní pa á run nítorí ogoji eniyan náà.”
30Ó bá tún wí pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, bí a bá rí ọgbọ̀n eniyan ńkọ́?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí ọgbọ̀n olódodo, n kò ní pa ìlú náà run.”
31Ó tún dáhùn pé “Jọ̀wọ́ dárí àfojúdi mi jì mí nítorí ọ̀rọ̀ mi, bí a bá rí ogún eniyan ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn pé, “Nítorí ti ogún eniyan, n kò ní pa á run.”
32Abrahamu tún dáhùn pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí ni ó kù tí n óo sọ̀rọ̀. Bí a bá rí eniyan mẹ́wàá ńkọ́?”
OLUWA tún dá a lóhùn pé, “N kò ní pa á run nítorí ti eniyan mẹ́wàá.” 33Nígbà tí OLUWA bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó bá tirẹ̀ lọ, Abrahamu náà bá pada sí ilé rẹ̀.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Learn More About Yoruba Bible