JẸNẸSISI 16
BM

JẸNẸSISI 16

16
Hagari ati Iṣimaeli
1Sarai, aya Abramu, kò bímọ fún un. Ṣugbọn ó ní ẹrubinrin ará Ijipti kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hagari. 2Ní ọjọ́ kan, Sarai pe Abramu, ó sọ fún un pé, “Ṣé o rí i pé OLUWA kò jẹ́ kí n bímọ, nítorí náà bá ẹrubinrin mi yìí lòpọ̀, ó le jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni n óo ti ní ọmọ.” Abramu sì gba ọ̀rọ̀ Sarai aya rẹ̀. 3Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti dé ilẹ̀ Kenaani ni Sarai, aya rẹ̀ fa Hagari, ará Ijipti, ẹrubinrin rẹ̀ fún un, láti fi ṣe aya. 4Abramu bá Hagari lòpọ̀, Hagari sì lóyún. Nígbà tí ó rí i pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú tẹmbẹlu Sarai, oluwa rẹ̀.
5Sarai bá sọ fún Abramu pé, “Ibi tí Hagari ń ṣe sí mi yìí yóo dà lé ọ lórí. Èmi ni mo fa ẹrubinrin mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó rí i pé òun lóyún tán, mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lójú rẹ̀. OLUWA ni yóo ṣe ìdájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ.”
6Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn pé, “Ṣebí ìkáwọ́ rẹ ni ẹrubinrin rẹ wà, ṣe é bí ó bá ti wù ọ́.” Sarai bá bẹ̀rẹ̀ sí fòòró ẹ̀mí Hagari, Hagari sì sá kúrò nílé.
7Angẹli OLUWA rí i lẹ́bàá orísun omi kan tí ó wà láàrin aṣálẹ̀ lọ́nà Ṣuri. 8Ó pè é, ó ní, “Hagari, ẹrubinrin Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo ni o sì ń lọ?” Hagari dáhùn pé, “Mò ń sálọ fún Sarai, oluwa mi ni.”
9Angẹli OLUWA náà wí fún un pé, “Pada tọ oluwa rẹ lọ, kí o sì tẹríba fún un.” 10Angẹli OLUWA náà tún wí fún un pé, “N óo sọ atọmọdọmọ rẹ di pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kì yóo le kà wọ́n tán. 11Wò ó! oyún tí ó wà ninu rẹ, ọkunrin ni o óo fi bí, o óo sọ ọmọ náà ní Iṣimaeli, nítorí OLUWA ti rí gbogbo ìyà tí ń jẹ ọ́. 12Oníjàgídíjàgan ẹ̀dá ni yóo jẹ́, bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó, yóo máa bá gbogbo eniyan jà, gbogbo eniyan yóo sì máa bá a jà, títa ni yóo sì takété sí àwọn ìbátan rẹ̀.”
13Nítorí náà, ó pe orúkọ OLUWA tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní “Ìwọ ni Ọlọrun tí ń rí nǹkan.” Nítorí ó wí pé, “Ṣé nítòótọ́ ni mo rí Ọlọrun, tí mo sì tún wà láàyè?” 14Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe orúkọ kànga náà ní Beeri-lahai-roi, ó wà láàrin Kadeṣi ati Beredi.
15Hagari bí ọmọkunrin kan fún Abramu, Abramu sì sọ ọmọ náà ní Iṣimaeli.#Gal 4:22. 16Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹrindinlaadọrun nígbà tí Hagari bí Iṣimaeli fún un.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Learn More About Yoruba Bible