JẸNẸSISI 12
BM

JẸNẸSISI 12

12
Ọlọrun Pe Abramu
1Ní ọjọ́ kan, Ọlọrun sọ fún Abramu pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, láàrin àwọn ìbátan rẹ, ati kúrò ní ilé baba rẹ lọ sí ilẹ̀ kan tí n óo fi hàn ọ́.#Ọgb 10:5; A. Apo 7:2-3; Heb 11:8 2N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, n óo bukun ọ, n óo sì sọ orúkọ rẹ di ńlá, tóbẹ́ẹ̀ tí o óo jẹ́ ibukun fún àwọn eniyan.#Gal 3:8 3N óo súre fún àwọn tí wọ́n bá súre fún ọ, bí ẹnikẹ́ni bá sì fi ọ́ bú, n óo fi òun náà bú. Nípasẹ̀ rẹ ni n óo bukun gbogbo ìdílé ayé.”
4Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún un, Lọti sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni ọdún marundinlọgọrin nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani. 5Abramu mú Sarai iyawo rẹ̀, ati Lọti, ọmọ arakunrin rẹ̀ lọ́wọ́ lọ, ati gbogbo ohun ìní wọn ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jẹ́ tiwọn ní Harani. Wọ́n jáde, wọ́n gbọ̀nà ilẹ̀ Kenaani.
Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Kenaani, 6Abramu la ilẹ̀ náà kọjá lọ sí ibi igi Oaku ti More, ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani ni wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà nígbà náà. 7Nígbà náà ni OLUWA fara han Abramu, ó wí pé, “Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA tí ó fara hàn án.#A. Apo 7:5; Gal 3:16. 8Lẹ́yìn náà Abramu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí orí òkè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó pàgọ́ sibẹ. Bẹtẹli wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ibùdó rẹ̀, Ai sì wà ní ìhà ìlà oòrùn. Ó tún tẹ́ pẹpẹ mìíràn níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. 9Abramu ṣá ń lọ sí ìhà gúsù ní agbègbè tí à ń pè ní Nẹgẹbu.
Abramu ní Ijipti
10Ní àkókò kan, ìyàn mú gidigidi ní ilẹ̀ Kenaani. Ìyàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí Abramu níláti kó lọ sí Ijipti, láti máa gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 11Nígbà tí ó ń wo Ijipti lókèèrè, ó sọ fún Sarai aya rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ náà mọ̀ pé arẹwà obinrin ni ọ́, 12ati pé bí àwọn ará Ijipti bá ti fi ojú kàn ọ́, wọn yóo wí pé, ‘Iyawo rẹ̀ nìyí’, wọn yóo pa mí, wọn yóo sì dá ọ sí. 13Wò ó, wí fún wọn pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wá, kí wọ́n lè ṣe mí dáradára, kí wọ́n má baà tìtorí rẹ pa mí.” 14Nígbà tí Abramu wọ Ijipti, àwọn ará Ijipti rí i pé arẹwà obinrin ni aya rẹ̀. 15Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Farao rí i, wọ́n pọ́n ọn lójú Farao, wọ́n sì mú un wá sí ààfin rẹ̀. 16Nítorí ti Sarai, Farao ṣe Abramu dáradára. Abramu di ẹni tí ó ní ọpọlọpọ aguntan, akọ mààlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, iranṣẹkunrin, iranṣẹbinrin, abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí.#Jẹn 20:2; 26:7.
17Ṣugbọn OLUWA fi àrùn burúkú bá Farao ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jà nítorí Sarai, aya Abramu. 18Farao bá pe Abramu, ó bi í pé, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí sí mi? Èéṣe tí o kò fi sọ fún mi pé iyawo rẹ ni Sarai? 19Èéṣe tí o fi sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni yín, tí o jẹ́ kí n fi ṣe aya? Iyawo rẹ nìyí, gba nǹkan rẹ, kí o sì máa lọ.” 20Farao bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì rí i pé Abramu jáde kúrò nílùú, ati òun ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Learn More About Yoruba Bible