ẸKISODU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
BM

ẸKISODU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Kí eniyan ṣídìí kúrò ní ibìkan lọ sí ibòmíràn ni à ń pè ní Ẹkisodu. Ìwé Ẹkisodu tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ pataki tí ó ṣẹ̀ ninu ìtàn ìgbésí ayé àwọn ọmọ Israẹli, èyí tí ó tọ́ka sí bí wọ́n ti kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí wọ́n ti ṣe àtìpó, tí wọ́n sì ti lò wọ́n nílò ẹrú. Ọ̀nà mẹrin pataki ni a lè pín ìtàn inú ìwé yìí sí: (1) Ìdásílẹ̀ àwọn Heberu kúrò lóko ẹrú; (2) Ìrìn àjò wọn sí orí òkè Sinai; (3) Majẹmu tí Ọlọrun bá àwọn eniyan rẹ̀ dá ní Sinai, tí ó sì fún wọn ní òfin nípa ìwà tí ó tọ̀nà láti máa hù, ìbáṣepọ̀ láàrin ara wọn ati òfin tí ó de ẹ̀sìn; (4) Kíkọ́ ati títo ilé ìjọ́sìn fún àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn òfin tí ó de àwọn alufaa ati ẹ̀sìn Ọlọrun.
Ní pataki, ìwé yìí ṣe àlàyé ohun tí Ọlọrun ṣe, bí ó ti kó àwọn eniyan rẹ̀ kúrò lóko ẹrú, tí ó sì sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè tí ó ní ìrètí òmìnira ati ìtura ní ọjọ́ iwájú, lẹ́yìn tí wọ́n kúrò lóko ẹrú.
Mose, ẹni tí Ọlọrun yàn láti kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde kúrò lóko ẹrú Ijipti, ni a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jù ninu ìwé náà. Ẹkisodu orí 20 níbi tí òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá wà ni ọ̀pọ̀ eniyan mọ̀ jù ninu ìwé Ẹkisodu.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Wọ́n dá àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ ní Ijipti 1:1–15:21
a. Oko ẹrú, ní Ijipti 1:1-22
b. Ìbí Mose ati ìgbà èwe rẹ̀ 2:1–4:31
d. Mose ati Aaroni kojú ọba Ijipti 5:1–11:10
e. Àjọ ìrékọjá ati bí wọ́n ṣe kúrò ní ilẹ̀ Ijipti 12:1–15:21
Ìrìn àjò láti Òkun Pupa dé orí òkè Sinai 15:22–18:27
Òfin ati majẹmu 19:1–24:18
Àgọ́ majẹmu ati àwọn ìlànà ìjọ́sìn 25:1–40:38

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Learn More About Yoruba Bible