YouVersion Logo
Search Icon

SAMUẸLI KEJI 1

1
Dafidi Gbọ́ nípa Ikú Saulu
1Lẹ́yìn ikú Saulu, nígbà tí Dafidi pada dé láti ojú ogun, níbi tí ó ti ṣẹgun àwọn ará Amaleki, ó dúró ní ìlú Sikilagi fún ọjọ́ meji. 2Ní ọjọ́ kẹta, ọdọmọkunrin kan wá, láti inú àgọ́ Saulu, ó ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sí orí, láti fi ìbànújẹ́ hàn. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. 3Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”
Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Láti inú àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli ni mo ti sá àsálà.”
4Dafidi wí fún un pé, “Sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún mi.”
Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Sísá ni àwọn ọmọ ogun Israẹli sá kúrò lójú ogun, ọpọlọpọ ninu wọn ni wọ́n sì ti pa; wọ́n ti pa Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ pẹlu.”
5Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ ti kú?”
6Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Orí òkè Giliboa ni mo wà, ni mo déédé rí Saulu tí ó fara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀. Mo sì rí i tí kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ọ̀tá ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ń lépa rẹ̀. 7Bí ó ti bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí. Mo sì dá a lóhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ 8Ó bi mí pé, ta ni mí; mo dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀kan ninu àwọn ará Amaleki ni mí.’ 9Saulu bá wí fún mi pé, ‘Sún mọ́ mi níhìn-ín, kí o pa mí, nítorí pé mo ti fara gbọgbẹ́, mò ń jẹ̀rora gidigidi, ṣugbọn ẹ̀mí mi ṣì wà sibẹ.’ 10Mo bá súnmọ́ Saulu, mo sì pa á. Nítorí mo mọ̀ pé, tí ó bá kúkú ṣubú lulẹ̀, yóo kú náà ni. Mo bá ṣí adé orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ni mo kó wá fún ọ yìí, Dafidi, oluwa mi.”#1 Sam 31:1-6; 1Kron 10:1-6
11Ni Dafidi ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn. 12Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan OLUWA nítorí pé ọpọlọpọ wọn ni wọ́n ti pa lójú ogun.
13Dafidi bèèrè lọ́wọ́ ọdọmọkunrin tí ó wá ròyìn fún un pé, “Níbo ni o ti wá?”
Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ará Amaleki kan, tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli ni mí.”
14Dafidi tún bi í pé, “Báwo ni ẹ̀rù kò ṣe bà ọ́ láti pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn?” 15Ni Dafidi bá pàṣẹ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, lọ pa ọdọmọkunrin ará Amaleki náà. Ọkunrin náà bá pa á. 16Dafidi wí fún ọdọmọkunrin ará Amaleki náà pé, “Ìwọ ni o fa èyí sí orí ara rẹ. Ìwọ ni o dá ara rẹ lẹ́bi, nípa jíjẹ́wọ́ pé, ìwọ ni o pa ọba, ẹni tí OLUWA fi àmì òróró yàn.”
Orin Arò tí Dafidi Kọ fún Saulu ati Jonatani
17Dafidi bá kọ orin arò fún Saulu, ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, 18ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ àwọn eniyan Juda ní orin náà. (Àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà ninu Ìwé Jaṣari.) Orin arò náà lọ báyìí:
19“A! Israẹli, wọ́n ti pa àwọn tí o fi ń ṣògo lórí àwọn òkè rẹ!
Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú!
20Ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀ ní Gati,
ẹ má ṣe ròyìn rẹ̀ ní ìgboro Aṣikeloni;
kí inú àwọn obinrin Filistini má baà dùn,
kí àwọn ọmọbinrin àwọn aláìkọlà má baà máa yọ̀.#Joṣ 10:13
21“Ẹ̀yin òkè Giliboa,
kí òjò má ṣe rọ̀ le yín lórí,
bẹ́ẹ̀ ni kí ìrì má ṣe sẹ̀ sórí yín,
kí èso kan má so mọ́ ní gbogbo orí òkè Giliboa,
nítorí pé, ibẹ̀ ni apata àwọn akikanju ti dípẹtà;
a kò sì fi òróró kun apata Saulu mọ́.
22Ọrun Jonatani kì í pada lásán,
bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í pada,
láì fi ẹnu kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa,
ati ọ̀rá àwọn akikanju.
23“Saulu ati Jonatani,
àyànfẹ́ ati eniyan rere,
wọn kì í ya ara wọn nígbà ayé wọn,
nígbà tí ikú sì dé,
wọn kò ya ara wọn.
Wọ́n yára ju àṣá lọ,
wọ́n sì lágbára ju kinniun lọ.
24“Ẹ̀yin obinrin Israẹli,
ẹ sọkún nítorí Saulu,
ẹni tí ó ro yín ní aṣọ elése àlùkò,
tí ó sì fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́.
25“Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú lójú ogun!
Jonatani ti ṣubú lulẹ̀,
wọ́n ti pa á lórí òkè.
26“Mò ń ṣe ìdárò rẹ,
Jonatani arakunrin mi;
o ṣọ̀wọ́n fún mi lọpọlọpọ.
Ìfẹ́ tí o ní sí mi, kò ṣe é fi ẹnu sọ,
ó ju ìfẹ́ obinrin lọ.
27“Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú,
tí àwọn ohun ìjà ogun sì ń ṣègbé!”

Currently Selected:

SAMUẸLI KEJI 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy