1
ÌWÉ ÒWE 11:25
Yoruba Bible
YCE
Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún, ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀, ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀.
Compare
Explore ÌWÉ ÒWE 11:25
2
ÌWÉ ÒWE 11:24
Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri, sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní, ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́, sibẹsibẹ aláìní ni.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:24
3
ÌWÉ ÒWE 11:2
Bí ìgbéraga bá wọlé, àbùkù a tẹ̀lé e, ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu àwọn onírẹ̀lẹ̀.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:2
4
ÌWÉ ÒWE 11:14
Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú, ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:14
5
ÌWÉ ÒWE 11:30
Èso olódodo ni igi ìyè, ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:30
6
ÌWÉ ÒWE 11:13
Olófòófó a máa tú àṣírí, ṣugbọn ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a máa pa àṣírí mọ́.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:13
7
ÌWÉ ÒWE 11:17
Ẹni tí ó ṣoore ṣe é fún ara rẹ̀, ẹni tí ó sì ń ṣìkà ó ń ṣe é fún ara rẹ̀.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:17
8
ÌWÉ ÒWE 11:28
Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóo rẹ̀ dànù bí òdòdó, ṣugbọn olódodo yóo rú bí ewé tútù.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:28
9
ÌWÉ ÒWE 11:4
Ọrọ̀ kò jámọ́ nǹkankan ní ọjọ́ ibinu, ṣugbọn òdodo a máa gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú
Explore ÌWÉ ÒWE 11:4
10
ÌWÉ ÒWE 11:3
Òtítọ́ inú àwọn olódodo a máa tọ́ wọn, ṣugbọn ìwà aiṣootọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ níí pa wọ́n.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:3
11
ÌWÉ ÒWE 11:22
Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni obinrin tí ó lẹ́wà tí kò ní làákàyè.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:22
12
ÌWÉ ÒWE 11:1
OLUWA kórìíra òṣùnwọ̀n èké, òṣùnwọ̀n tí ó péye ni inú rẹ̀ dùn sí.
Explore ÌWÉ ÒWE 11:1
Home
Bible
Plans
Videos